Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti America jíròrò lórí Àtúnsẹ òfin ìdìbò, epo rọ̀bì àti dídá ẹ̀rọ ayélujára twitter dúró

Ademọla Adepọju

131

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì  fún mínísítà tó ń mójútó èrọ ayélujára àti ìbáraẹnisèpọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Umar Gwandu, ti sọ pé mínísítà fún ètò ìdájọ́, Abubakar Malami SAN, gbàlejò asojú orílẹ̀-èdè ilẹ́ Britain lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Iyaafin Catriona Laing ní ọjọ́bọ̀, ní ìlú Abuja.

Umar Gwandu sọ pé ìpàdé tí wọ́n se fún ẃakàtí kan gbáko naa ni wọ́n fi jírórò lórí: ipolongo lori iwa ibajẹ, atunse si ofin idibo, didena nipa jiji owo lati ilu kan si omiran, atunse ofin to rọ mọ epo rọbi, fifi ofin de ẹrọ ayelujara twitter, didena awọn iwa ọdaran lorisirisi.

O tun tẹsiwaju pe, ipinnu aarẹ Muhammadu Buhari ni lati peṣe awọn awujọ to se e gbe fun awọn to ba nifẹẹ lati da ile-se tabi  oko-owo silẹ lorilẹ ede Naijiria, ati lati pese eto aabo to gbonjẹ fẹgbẹ gbawo bọ,fun gbogbo awọn eniyan to n gbe ni jake-jado orilẹ-ede Naijiria.

Lori awọn ile-isẹ epo rọbi, Minisita naa sọ pe awọn igbesẹ ti o yẹ ni wọn ti gbe lati se aridaju pe aare Buhari fọwọsi ofin ti awọn ilẹ igbimọ asofin fi ẹnu ko le lori.

Malami tun tesiwaju pe atunse eto ofin idibo ti wọn se yoo jẹ ki, eto idajọ ati eto ijọba tiwantiwa lorilẹ ede Naijiria tubọ fẹsẹ mulẹ sii.

 

 

 

 

Hamzat Roshidat

Leave A Reply

Your email address will not be published.