Take a fresh look at your lifestyle.

ILE-ISẸ OLOGUN KO NI PARIWO AYẸYẸ WỌN TI ỌDUN 2021

Ademọla Adepọju

107

adari ile-isẹ ologun orilẹ-ede Naijiria, Ọgagun Faruk Yahaya ,  ti sọ pe ayẹyẹ wọn ti ọdun yii ko ni jẹ alariwo, Ọgagun Yahaya  salaye yii fun awọn oniroyin lori bi ayẹyẹ ọdun yii yoo se waye.

O sọ pe iku Ologbe Ọgagun Ibrahim Attahiru ati awọn mewaa miran ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu ni Ọjọ ọkanlelogun, osu karunun, ọdun 2021 lo sokunfa idi ti ayẹyẹ ọdun yii ko se ni jẹ alariwo.

Ayẹyẹ wọn ti ọdun yii ni yoo se afihan isẹ ti wọn se ni ọdun to kọja, ti yoo si tun sọ bi ti ọdun to n bọ yoo se ri.

Lara awọn nnkan ti wọn fe se lati fi se ayẹyẹ naa ni: Kiki irun Jimọ ni gbogbo ẹka mosalasi awọn ikọ ọmọ ologun to wa ni jake-jado orilẹ-ede Naijiria ni ọjọ keji, osu keje, ọdun 2021.

Bakan naa, ni gbogbo awọn ile ijọsin onigbagbọ yoo maa jọsin papọ ni gbogbo awọn ẹka  ile-ijosin ti ikọ ọmọ ologun ni ọjọ kẹrin, osu keje, ọdun 2021.

Lara eto ti ile-isẹ ologun yoo fi sami ayẹyẹ ti ọdun 2021 yii ni pipese eto iranwọ fun awọn ara ilu lati jẹ anfani eto ilera ni awọn agbegbe ti wọn ti la silẹ ni eyi ti yoo bẹrẹ ni ọjọ karun,osu keje, ọdun 2021 ti a wa yii.

 

 

 

Hamzat Roshidat

Leave A Reply

Your email address will not be published.