Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ fi àwọn Itsekiri sẹ́nu isẹ́ àti ipò ìjọba apapọ̀

90

Àwọn adarí ẹgbẹ́ òsèlú tó ń se ìjoba lọ́wọ́ lọwọ báyìí, All Progressives Congress (APC) ti Itsekiri ti rọ ì̀jọba apapọ̀  láti  maa fi awọn ọmọ  Itsekiri  sínú ipò ati lati bá ìjọba àpapọ̀ se isẹ́ papọ̀.

Adari ẹgbẹ oselu APC  sọrọ yii lasiko ipade to waye ni Koko, ni ijọba ibilẹ Ariwa iwọ oorun Warri ti o jẹ olu-ilu ipinlẹ Delta .

WỌn tun wa rọ aare  Muhammadu Buhari  “lati pasẹ ”  fun awọn to n se iwadii lori eto inawo ti ajọ to n mojuto awọn ipinlẹ ti wọn ti n wa epo rọbi lati tete pari isẹ́ wọn.

Alex Ideh,ti o ti fi igba kan jẹ Kọmisọna fun agbegbe naa lẹẹkeji lo pe ipade ọhun, o tun wa rọ gbogbo awọn adari ẹgbẹ oselu  APC , ti wọn jẹ ọmọbibi ilu  Itsekiri  lati fọwọsowọpọ , ki wọn si se ara wọn ni ọkan  , ki wọn lee jẹ anfaani ipo lati ọdọ ijọba apapọ.

lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni Ologbotsere ti Warri ,oloye Ayirimi Emami, oloye Michael Odeli; Comrade Alex Eyengho wati awọn adari ẹgbẹ oselu  APC.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.