Take a fresh look at your lifestyle.

”IPOB: A ò ní dá gbogbo àwọn tó bá fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Kanu sílẹ̀ ”- Lai Mohammed

110

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti ní gbogbo àwọn  tó ran adarí ajìjàgbara àti olùdarí IPOB lọ́wọ́ láti se isẹ́ ibi , ni àwon kò ní fi sílẹ̀ , bó se wù kí wọ́n wà ni ipò tó ga tó

Minisita fun iroyin ati asa lorilẹ ede Naijiria , Alhaji Lai Mohammed lo so eleyii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja lojọ Ẹti.

Mohammed tẹsiwaju pe awọn alasẹ ti bẹrẹ isẹ́ iwadii lati ri i pe wọn mu gbogbo  awọn to jẹ onigbọnwọ fun Kanu , yala awọn eniyan, ẹgbẹ tabi ile-isẹ́.,

Bo tilẹ jẹ pe ijọba orilẹ ede Naijiria , ko sọ orilẹ ede ti wọn ti mu Kanu wa si orilẹ ede Naijiria, sugbọn minisita tẹpẹmọ ọrọ rẹ pe igbiyanju awọn agbofinro ati awọn ọtẹlẹmuyẹ pẹlu awọn orilẹ ede ti wọn fọwọsowọpọ pẹlu orilẹ ede Naijiria, ni wọn se ri Nnamdi Kanu wa si orilẹ ede Naijria.

 Naijiria tun fi ọwọ sinku  mu  Ogbeni Nnamdi Kanu pada ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2021, lati tun bẹrẹ igbẹjọ rẹ ni orilẹ-ede Naijiria. wọn   tun gbee lọ si kootu ,ki  wọn lee gbàsẹ  lọwọ ile-ẹjọ lati wa ni i atimọle awọn agbofinro  DSS, di igba ti igbẹjọ  rẹ yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹrindinlọgbọn ati ọjọ kẹtadinlọgbọn , osu keje, ọdun 2021.

Kanu ni wọn sọ pe o sa kuro lorilẹ ede Naijiria lọdun 2017  lasiko igbẹjọ rẹ . Ni bayii, ẹ̀sùn mọkanla ni ijọba orilẹ ede Naijria, fi kan Nnamdi Kan , lara rẹ ni ẹsun ifipa-gbajọba, ipaniyan, iwa ọdaran, gbigbe awọn ẹrù to lodi wọle ati awọn ẹsun miran.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.