Take a fresh look at your lifestyle.

Mítà iná mọ̀nàmọ́ná mílíọ́nù mẹ́fà lóti wà nílẹ̀ fún àwọn ará ìlú báyìí

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

30

Olùdárí Alákóso, Ilé-iṣẹ́ tó ń  ṣàkóso iná mọ̀nàmọ́ná ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NEMSA àti ọ̀ga àgbà Olùyẹ̀wò iná mọ̀nàmọ́ná lápapọ̀, Peter Ewesor sọ pé, Ìjọba  ti gbèrò láti gbé  àwọn mítà iná mọ̀nàmọ́ná tí ó tó mílíọ́nù mẹ́fà, tí wọ́n ti sanwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ jáde  jákèjádò orílẹ̀-èdè.

O ṣe ifitonileti yii lakoko ti wọn n ṣe Apejọ ounjẹ ọsan   oloṣooṣu ti Bureau of Public Service Reform ṣagbekalẹ rẹ ni Abuja,olu –ilu orilẹ-ede.

Gẹgẹ bii o ti wi,fifun awọn eniyan ni mita naa yoo wa ni ipele mẹrin.O sọ siwaju pe, gbogbo mita ti wọn ba gbe wa si agbegbe onikaluku laisi ontẹ NEMSA ati ami rẹ, ko tii ṣe lo niyẹn.

Oludari Alakoso tẹnumọ pe, awọn ọmọ Naijiria ni ẹtọ lati kọ iru awọn mita bayii .

Oga NEMSA, nitorinaa, gba awọn ọmọ Naijiria niyanju lati jabo awọn ijamba itanna tabi eyikeyi iru eewu ina fun awọn ile-iṣẹ to n pin mita  naa ni  kaakiri.

Leave A Reply

Your email address will not be published.