Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ sẹun ẹ̀yin kọmisọna,ẹ wá máa lọ sílée yín,Gomina Seyi Makinde tú ìgbìmọ̀ ìjọba rẹ̀ ká

Ademọla Adepọju

101

Gomina ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti se àtúntò  ìgbìmọ̀ alásẹ rẹ̀, nígbà tí ó tú wọn ká, léyìn ìpàdé wákàtí márùn ún ti o ṣe   pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ alásẹ ọ̀hún ní ọjọ́ ìsẹ́gun, ọjọ́ kọkandinlọgbọn osu kẹfa ọdún yii.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Taiwo Adisa fi sita lo salaye awọn ti  atunto ile ohun kan bi olori osisẹ (Chief of Staff) ati awọn komisana mẹtadinlogun. Ninu eyi ti awọn igbimọ alasẹ to sẹku  je akọwe ijọba (SSG), Oludari osisẹ ijọba (HOS), Oludari  Ilana Lamẹẹto ( DG Due Process)

Gomina Makinde fi ẹ̀mí imoore han si awọn igbimọ alasẹ rẹ, ni pataki julọ  awon ti ọrọ naa kan, ti o si gba ladura pe ki Eleduwa ran wọn lọwọ lati tẹsiwaju lati ma se rere ninu idawọle won gbogbo. Bakan naa, lo lu wọn lọgọ ẹnu fun ẹmi ifọkansin ti wọn fi sisẹ fun bi i ọdun meji sẹyin lati mu ipinẹ Oyo kuro ninu òsì bọ sinu ọrọ̀.

O tun salaye siwaju fun awon komisana metadinlogun ohun pe, o ti to asiko lati se ayewo atupale ati atunto ile lati le tesiwaju ninu erongba re lati mu ipinle Ọyọ dagbasoke.

Igbimo alase ohun ni gomina yan ni ojo kerinla osu kejo odun 2019 (14/08/2019) lati ba sisẹ lẹyin ti o jawe olubori ninu eto  idibo  gomina eleyii to waye ni ọjọ kẹsan osu keta odun 2019, (09/03/2019).

 

Abiola Olowe.

Ibadan

Leave A Reply

Your email address will not be published.