Ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà kí Orílè-èdè Ṣáínà fún àjọ̀dún ọgọ́rún ọdún ẹgbẹ́ Kọ̀múnísítì
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Mùhámmádù Bùhárí ti ránṣẹ́ ìkíni sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Ṣáínà, ààrẹ Xi Jinping lórí ayẹyẹ àjọyọ̀ ọgọ́rùún ọdún tí wọ́n dá ẹgbẹ́ kọ̀múnísítì ti Ṣáínà sílẹ̀.
Ninu lẹta rẹ kan si adari Ilu Ṣaina, aarẹ sọ pe Saina ti ṣaṣeyọri ni ipese “awujọ alafia niwọntun wọnsi” ati pe o n la ọna lati pese “orilẹ-ede ti yoo wa ni ẹlẹgbẹ awujọ ode oni.
Aarẹ Buhari tun tẹnumọ pe, awọn ibaṣe laarin awọn orilẹ-ede mejeeji “Ti fidi oṣelu ifọkantan to n gbilẹ si laarin wọn mulẹ,ibaraẹniṣepọ ọrọ aje ati iṣowo ti awọn ilu mejeeji n janfaniẹ ati ọlọkan ọjọkan pasipaarọ awọn eniyan laarin orilẹ-ede mejeeji bakannaa.
Leave a Reply