Take a fresh look at your lifestyle.

Olùdarí Ilé Aṣòfin Eko kí Gómínà, Sanwo-Olu àti Gbajabiamila kú ọjọ́ ìbí

Lanre Lagada-Abayọmi

55

Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti kí Gomina Sanwo-Olu ti Ìpínlẹ̀ Èkó kú orí ire ọjọ́ ìbí ọdùn kẹrìndínlọ́gọ́ta (56) rẹ̀. Ó ṣàpéjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú Ìpínlẹ̀ Èkó.

Ọbasa ninu ọrọ rẹ lati ọwọ alukoro rẹ sọ pe igbesẹ Gomina naa ti ran ipinlẹ yii lọwọ lati si wa ni ipo aṣiwaju to wa lorilẹ-ede Naijiria.

Aṣofin Ọbasa wa gboriyin fun ibaṣepọ to dan mọran to wa laarin ẹka amuṣẹṣe ati ẹka aṣofin ijọba, eleyii ti atunbọtan rẹ n mu aṣeyori ba akitiyan ijọba ipinlẹ yii. O ni:

“Mo ki akikanju Gomina wa ku oriire, ẹni ti o n fi gbogbo ara ṣiṣẹ fun idagbasoke ipinlẹ Eko. Ipinlẹ wa n dunnu fun awọn olori rere ti wọn ni ẹmi ilọsiwaju ipinlẹ yii lọkan, eyi ti o jẹ ọkan ninu wọn. Laarin ọdun to kọja mo jẹrii si i pe ibaṣepọ to dan mọran wa laarin ẹka amuṣẹṣe ati ẹka aṣofin ijọba Ipinlẹ Eko, eleyii ti iwọ ati igbimọ alakoso ijọba rẹ fẹsẹ rẹ mulẹ.

Mo tun sọ pe abuda ti ko lafiwe, bii ọgbọn ori ati okun ti Ọlọrun fi jinki ẹ jẹ ohun ti o fi n ṣaṣeyori ninu iṣẹ rẹ gẹgẹ bi Gomina. Mo fẹ fi ye ẹ pe iwa tẹgbọntaburo awa mejeeji si wa nibẹ, paapaa fun ilọsiwaju Ipinlẹ Eko ni orilẹ-ede Naijiria, ti awọn olugbe ipinlẹ yii yoo fi wa ni irẹpọ pẹlu ara wọn.”

Nigba ti o n ṣeleri pe Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko yoo tẹ siwaju lati maa fọwọsowọpọ pẹlu ẹka amuṣẹṣe ipinlẹ yii. O wa rọ Gomina lati ri ọjọ ibi rẹ gẹgẹ bi igba akọtun lati ọwọ Ọlọrun lati le fi okun rẹ dari ọkọ ipinlẹ yii de ebute aṣeyọri.

Ẹwẹ, Aṣofin Ọbasa tun ki Agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣojuṣofin orilẹ-ede yii, Aṣofin Fẹmi Gbajabiamila ku oriire ọjọ ibi ọdun mọkandinlọgọta (59) tirẹ lori ilẹ. O ki i fun iṣẹ takuntakun rẹ lati ri i daju pe Ile Igbimọ Aṣojuṣofin yii n ṣe ohun gbogbo letoleto. O ni

“Iṣẹ aṣeyori rẹ ninu Ile Igbimọ Aṣojuṣofin ti fi ẹsẹ oṣelu tiwantiwa mulẹ lorilẹ-ede yii. Mo ki ẹ ku oriire. Aṣeyi ṣọpọ ọdun laye, pẹlu alaafia.”

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.