Take a fresh look at your lifestyle.

Agbègbè mẹ́tàdínlógún nínú mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lati gbà padà lọ́wọ́ ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ Boko Haram-ọgagun Faruk Yahaya

Ademọla Adepọju

43

Adarí ilé isẹ́ ológun lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà, ọ̀gágun Faruk Yahaya  ti ní agbègbè mẹ́tàdínlógún nínú mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ Boko Haram ti lé àwọn tó ń gbé níbẹ̀ kúrò ni àwọn ti gbà padà lọ́wọ́ ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ Boko Haram.

ilé- isẹ́ ológun tun ni awọn yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adari ìbílẹ̀ láti leè tẹpẹlẹmọ́ àseyọrí lọ́nà àti sẹ́gun ikọ̀ Boko Haram àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ní ẹkùn Ariwa. .

Ọgagun Yahaya sọrọ lọjọ Ẹti lasiko to n  se ibẹwo si Shehu ti Borno, ọba ọlọla julọ, Alhaji Abubakar Garbai El-kanemi, CFR  ati awọn igbimọ rẹ ni aafin ọba to wa niluu  Maiduguri,ni ipinlẹ  Borno .

Shehu ti  Borno, Alhaji Abubakar Garbai El-kanemi, wa gbosuba fun ile- isẹ ologun fun alaafia ti o ti bẹrẹ si n jọba ni ẹkun Ariwa.

Shehu tun wa seleri pe gbogbo ọmọ ipinlẹ Borno ni yoo satilẹyin fun ile-isẹ ologun lati lee se aseyọri nipa gbigbogun ti ikọ ọlọtẹ Boko Haram ati awọn ọdaran to n da omi alaafia ipinlẹ naa rùú.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.