Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò túnbọ̀ tẹra mọ́ ìdókòwò wọn pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Bẹ́ljíọ́mù

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

77

Aṣojú orílẹ̀-èdè  Nàìjíríà sí Bẹ́ljíọ́mù, Obinna Onowu, ti ṣèlérí láti jẹ́ kí àjọṣepọ̀  ọrọ̀-ajé jinlẹ̀ láàrin Nàìjíríà àti Bẹ́ljíọ́mù jákèjádò gbogbo àwọn ẹ̀ka.

Ọgbẹni Onowu sọ eyi lakoko ti o n fi awọn iwe-ẹri  han  Ọba Philippe kinni,iyẹn Ọba  Belijiomu, ni aafin rẹ ni Burusẹli.

Gẹgẹ bi alaye kan ti Iyaafin Olamide Adediran, Oludamoran, aṣoju orilẹ-ede Naijiria, ni  Burusẹli ṣe  fun awọn akọroyin ni ilu Abuja, Onowu jẹrisi  awọn  ibaṣe to wa tẹlẹ laarin awọn orilẹ-ede mejeeji ati pataki  atunbọ maa

fọwọsowọpọ  sii.

O ṣe ileri lati mu ki  ajọṣepọ awọn orilẹ-ede mejeeji jinlẹ   si, paapaa julọ, ni awọn agbegbe  iṣowo ati idokowo, igbaradi, eto-ẹkọ, ilera ati Imọ-ẹrọ amayedẹrun .

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.