Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó fọwọ́sí àbádòfin tó de ọjà fífi ẹya ara ènìyàn ṣòwò, ní ìgbà kejì

Lanre Lagada-Abayọmi

0 360

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó ti fọwọ́sí àbádòfin tó fòfin de ọjà fífi ẹ̀yà ara ènìyàn ṣòwò ní Ìpínlẹ̀ yìí, ní ìgbà kejì. Agbẹnusọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣòfin Mudashiru Ọbasa ṣàpéjúwe àbádòfin náà gẹ́gẹ́ bí èyí tó dára púpọ̀ fún Ìpínlẹ̀ yìí.

Ki wọn to da abadofin naa pada fun igbimọ to n mojuto Eto Ilera ninu Ile, Aṣofin Ọbasa pe fun fifi abala ofin kun abadofin naa, ti yoo fofin de iwa fifi eniyan ṣoogun.

O wa pa a laṣẹ pe ki wọn wo ofin to nii ṣe pẹlu iwa ọdaran, ki wọn le fi wo abadofin to jẹ mọ tita ẹya ara eni tabi ṣiṣe ayipada ẹya ara yii.

Ṣaaju eyi, Alaga Igbimọ to n moju to Eto Ilera ninu Ile Aṣofin naa, Aṣofin Hakeem Ṣokunle ṣalaye pe abadofin naa tun wo ofin to nii ṣe pẹlu ilana ṣiṣe ayipada ẹya ara ati ẹni ti o fi ẹya ara tirẹ silẹ fun iṣẹ abẹ yii.

Aṣofin Ṣokunle sọ pe abadofin yii ni abala meje pẹlu abala keekeeke mẹtadinlogoji, pẹlu igbesẹ lati gegi dina fifi ẹya ara ṣowọ lai bofin mu.

Labẹ abadofin naa, ẹnikẹni to ba yọ ẹya ara ẹlomiiran lọna aitọ yoo jẹbi ẹsun yii, pẹlu ẹwọn ọdun mẹwaa. Ile iwosan to ba si ṣe iru eyi yoo san owo itanran miliọọnu marun-un tabi ki o lọ ẹwọn ọdun mẹwaa.

Ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Gbọlahan Yishawu sọ pe bi abadofin yii ba di ofin, yoo le gegi dina fifi ẹya ara ṣowo.

Aṣofin Rotimi Olowo bẹnu atẹ lu iwa fifi ẹya ara ṣowo, ati pe abadofin naa yoo le fopin si iwa naa, yoo si daabo bo awọn ọmọde ati awọn alarun ọpọlọ. Ati pe ijiya ti wọn fi sinu ofin yii fun awọn to n wu iru iwa ibi bayii yẹ ko pọ ju bẹẹ lọ.

Aṣofin Olowo sọ pe pipese abala fun fifọwọ si awọn ile iṣayẹwo ti yoo maa ṣiṣẹ to jẹ mo eyi ṣe pataki lati dẹkun awọn asawọ to fẹ ṣiṣẹ ọun, ṣugbọn ti won ko nimọ to yẹ.

Igbakeji Agbẹnusọ Ile Aṣofin naa, Aṣofin Wasiu Eshilokun-Sanni bẹnu atẹ lu iwa fifi ẹya ara eniyan ṣowo ni orilẹ-ede Naijiria, o wa rọ awọn akẹgbẹ rẹ lati ṣatilẹyin fun abadofin naa.

Aṣiwaju ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ ninu Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Sanai Agunbiade, ṣapejuwe abadofin naa gẹgẹ bi eyi to fi itara ijọba ipinlẹ yii han fun ifẹ wọn si awọn ara ilu. Nigba ti o n ṣayẹwo abadofin naa, o ṣalaye pe eleyii yoo le jẹ ki ṣiṣe ayipada ẹya ara wa ni ọna to tọ, ti yoo si dẹkun fifi ẹya ara ṣowo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button