Take a fresh look at your lifestyle.

Nàíjíríà tún ti ní Fáfitì tuntun méjì, àwọn mẹ́rin míràn tún ti gba ìgbega

37

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjírìà ti kéde àwọn Fáfitì ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun méjì  míràn ní ìpínlẹ̀ Jigawa àti Akwa Ibom, nígbà tí wọn yóò tún mú ètò ìdàgbàsókè  bá àwọn Fáfitì mẹ́rin míràn lórílẹ̀ èdè Nàíjírìà.

Akọwe agba fun ajọ to n mojuto eto ẹkọ lorilẹ ede Naijiria,Sonny Echono lọ sọrọ yii niluu Abuja lọjọ Aje, lasiko to n soju fun minista fun eto ẹkọ lorilẹ ede Naijiria , Malam Adamu Adamu,

Adamu tun sọ pe ijọba yoo tun da ile-ẹkọ imọ ẹrọ ,iyẹn , National Institute of Technology (NIT)silẹ niluu Abuja fun awọn akẹkọọ to ba tun fẹ gboye sii ,ninu ẹkọ wọn.

O tun salaye pe ,Ile ẹkọ imọ ẹrọ to wa ni Yola (Ariwa Ila-oorun), Akure (Guusu Iwọ oorun guusu), Owerri (Guusu ila oorun) ati Minna (Aarin gbungbun ) ni awọn yoo tun ṣeto idagbasoke lori wọn.

“Bakan naa , ni ijoba yoo tun seto idagbasoke si awon Fafiti imọ ẹrọ  to wa ni ipinlẹ Jigawa ati Akwa Ibom .

Adamu tẹsiwaju pe ajọ to n mojuto eto ilera,imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ ati ile-isẹ FCT , Abuja ati awọn ajọ miran ni yoo jọ fọwọsowọpọ lati jọ se agbatẹru eto yii.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.