Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ ọmọ ogun Nàíjíríà mú afurasí ọ̀daràn pẹ̀lú àwọn irinsẹ́ ológun tó ẁa ní ìkáwọ́ rẹ̀

Ademọla Adepọju

119

Ikọ̀ ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàíjíríà tí wọ́n wà ní ojú ọ̀nà Mokwa-Jebba  ti mú afurasí ọ̀daràn kan pẹ̀lú àwọn irinsẹ́ ológun tó ẁa ní ìkáwọ́ rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń yẹ awọn ọkọ̀ tó bá ń kọjá wò.

Òpòpónà márosẹ̀  Mokwa-Jebba ni pupọ awọn arinrinajo sabaa maa n gba lọ si ilu Abuja ati Ilorin,ni ipinlẹ  Kwara .

Agbẹnusọ ile-isẹ ologun lorilẹ ede Naijiria,ọgagun Onyema Nwachukwu sọ pe ”ni deede aago mẹsan owurọ ni awọn ikọ ọmọ ogun orilẹ ede yii da ọkọ kan to n bọ lati  Zuru lọ si ilu  Ibadan, ni ipinlẹ Oyo duro , nigba ti ikọ ọmọ ogun  yii ri awakọ ọhun , ti o pe ara rẹ ni ,Aminu Sule pe ọkan lara  osisẹ ọmọ ogun orilẹ ede yii ni oun, lasiko ti wọn bẹrẹ si n yẹ ọkọ ti arakunrin naa n wa wo, ni wọn ri asọ ologun, bata, ọbẹ ati awọn òògùn ninu ọkọ naa..”

Nigba ti wọn bẹrẹ si ni n fi ọ̀rọ̀ wa ọkunrin  naa wo , ni  o jẹ́wọ́ pe oun, n lọ si ilu Ogbomosho ni ipinlẹ Oyo .Afurasi naa tun jẹwọ pe,ẹgbọn oun, ti o jẹ ọkan lara osisẹ ologun orilẹ ede yii  lo ni  asọ ologun naa.

Amọsa, nigba ti ikọ ọmọ ogun tẹsiwaju ninu iwadii wọn, lo fihan pe irọ patapata ni afurasi naa n pa, o sa kuro ni ipinlẹ Niger lati lọ fara pamọ si ibomiran ni.Nitori ọwọ lile ti ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria n gbe lati ri i pe wọn mu gbogbo awọn ọlọtẹ ati ọdaran ti wọn n da omi alaafia ipinlẹ Niger rú.

Afurasi naa si ti wa ni agọ ọlọpaa to wa ni Mokwa  bayii lati tẹsiwaju ninu isẹ iwadii wọn.

Adari ile-isẹ ologun orilẹ ede Naijiria, ọgagun  Faruk Yahaya,ti fọkan gbogbo awọn to n gbe ni ipinlẹ  Niger  ati gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria balẹ pe ko sewu lẹ́gbẹ̀rún ẹ̀kọ mọ, pe aabo to peye ti wa fun dukia ati ẹmi wọn.

O wa rọ gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria ki wọn máa se kaarẹ lati maa fi to awọn agbofinro leti ti wọn ba fura si awọn ọdaran kan ni agbegbe wọn, ki wọn si maa fọwọsowọpọ pẹlu ile-isẹ ọmọ ogun nipa fifun wọn ni awọn iroyin to lee ran wọn lọwọ lati tubọ maa fi daabo bo wọn.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.