Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀yin ọ̀dọ́ olósèlú, ẹ rọ àwọn akẹ́gbẹ́ yín láti darapọ̀ mọ́ ètò òsèlú-Osinbajo

Ademọla Adepọju

72

Igbákejì ààrẹ orilẹ èdè Naijiria, ọjọgbọn  Yemi Osinbajo ti ni àwọn ọ̀dọ́ ni yóò kó ipa pàtàkì láti sàtúnse tó mọnyá lórí ètò ìsèlú , ìdàgbàsókè àti ohun tó leè mú kí ìsọ̀kan orílẹ̀ èdè Naijiriatúbọ̀ fẹsẹ̀ mulẹ sí i.

Ọjọgbọn Osinbajo sọrọ yii niluu Abuja lọjọ Aje nibi ibẹrẹ eto ti awọn ọdọ inu ẹgbẹ oselu  APC, Progressive Youth Conference  se ni gbọngan igbalejo  International Conference Centre.

Igbakeji aarẹ ti o jẹ ọkan lara alejo  pataki nibi ipade ọhun , ti wọn pe akọle rẹ ni , “Ìpínnu kan ni ọjọ́ iwájú jẹ́ ,”  tun sọ pe, ti pupọ awọn ọdọ ba darapọ mọ eto iselu , ni yoo tubọ jẹ ki wọn lee kopa pataki lati mu atunse to mọnyan lori, ba  orilẹ ede Naijiria.

O wa rọ awọn ọdọ ki wọn tubọ maa rọ awọn akẹgbẹ wọn lati kopa ninu eto iselu orilẹ ede Naijiria.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.