Take a fresh look at your lifestyle.

A ó parí afárá kejì ti Niger lọ́dún tó ń bọ̀ – Babatunde Fashola

Ademóla Ademóla

73

Mínísítà fún ètò isẹ́ ati ilé gbígbé ,  Babatunde Fashola,ti ní àwọn yóò parí afárá kejì ti Niger tí wọ́n ń se lọ́wọ́-lọ́wọ́ báyìí  lọ́dún tó ń bọ̀ .

Minisita sọrọ yii lasiko ifọrọwerọ to se pẹlu ile-isẹ iroyin ,News Agency of Nigeria (NAN)niluu Abuja lọjọ Aiku lati sami ayẹyẹ ọdun kẹfa ti o di minisita.

Gẹgẹ bi Fashola se sọ, o ni ti awọn ba pari afara  ọhun, yoo so ila oorun Guusu ati iwọ oorun Gusu papọ̀.

Bakan naa , ni afara ọhun yoo tun jẹ ki idagbasoke ba eto ọrọ̀ aje ila oorun ati iwọ  oorun gusu orilẹ ede Naijiria.

Afara ọhun ni o bẹrẹ  lati Asaba ni ipinlẹ Delta lọ si Ozubulu, Ogbaru ati awọn agbegbe miran ni ipinlẹ Anambra .

Lọdun 1965 ni ile-isẹ Dumez , ti wọn jẹ ẹya Faranse ní wọn  kọ afara akọkọ ti  Niger ti wọn n  lo bayii , ni eyi ti o so Onitsha ati Asaba papọ̀.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.