Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó rọ ìjọba àpapọ̀ láti ṣàtúnṣe sí ìwé òfin Nàíjíríà,kí wọ́n sì jíròrò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n pé fún òmìnira ẹkùn wọn

Lanre Lagada-Abayọmi

28

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti rọ ijọba apapọ lati ṣatunto orilẹ-ede Naijiria, ki agbara ma fi si ọdọ ijọba apapọ nikan, paapaa nipa ṣiṣe atunṣe kikun si iwe ofin orilẹ-ede yii, ki wọn si jokoo ijiroro pẹlu awọn ti wọn pe fun ominira ẹkun wọn.

Aba yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Igbimọ Aṣofin naa jiroro le lori lẹyin ti Alukoro agba Ile naa, Aṣofin Setonji David mu aba naa wa lori ayajọ ijọba tiwantiwa ti ọdun 2021, eyi ti o pe ọdun mejilelogun orilẹ-ede Naijiria laisi ikọsẹ.

Amofin David ninu aba to da naa, fi mulẹ pe akitiyan fifi ẹsẹ oṣelu tiwantiwa mulẹ jẹ eso rere awọn akin olori wa ti wọn ti ba akitiyan yii lọ, ati awọn miiran to si wa laye ninu wọn. O ni ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun yii ṣe pataki paapaa ninu itan orilẹ-ede Naijiria, to jẹ ọjọ ti eto idibo yoo waye ni wọọrọwo julọ lalai si magomago ninu.

O ni iṣakoso ijọba tiwantiwa yii ti ṣanfani nla fun orilẹ-ede Naijiria paapaa ni ti idagbasoke ilu, ẹtọ ọmọniyan ati iwulo ẹka aṣofin.

Ẹwẹ, Aṣofin David ba ọkan jẹ pe bo tilẹ ṣe pe ijọba awaarawa ṣanfani fun orilẹ-ede yii, sibẹ ọpọ ipenija ni a n koju, paapaa ni ti eto aabo to mẹhẹ, eleyii ti awọn adunkookomoni, adigunjale, amuninigbekun, awọn dẹrandẹran ti ṣeku pa ọpọ eniyan, ti wọn si ti sọ ọgọọrọ awọn eniyan di alainilelori. O ni eredii gbogbo ipenija yii ko ṣẹyin aini ijọba apapọ tootọ, ati aisi pinpin agbara lododo. Fun idi eyi, o ṣe pataki lati ṣe atunṣe si iwe ofin orilẹ-ede yii, eleyii to jẹ iṣẹ ọwọ awọn ologun nigba naa, ti o si n ṣakoba fun ilọsiwaju orilẹ-ede yii.

Lẹyin ti o kin aba naa lẹyin, Aṣofin Bisi Yusuff sọ pe niwọn to jẹ pe ijọba ologun nigba naa lo ṣe ofin ọdun 1999 naa, dandan ni ko ta ko ilana ijọba tiwantiwa, eyi ti ko jẹ ki orilẹ-ede yii ṣe daradara pẹlu iwe ofin yii.

Aṣofin Lukmoh Olumoh ninu ọrọ rẹ, sọ pe ijọba ologun lo ṣokun fa gbogbo ipenija ti a n koju bayii, eleyii ti o ti ṣakoba fun eso rere ijọba tiwantiwa

Ninu ọrọ Aṣofin Rotimi Olowo, o ṣalaye pe iwe ofin ọdun 1999 naa jẹ iṣẹ ọwọ ijọba ologun igba naa, lati le jẹ ki awọn ara ilu tẹwọ gba ofin naa.  O ni bo tilẹ ṣe pe wọn ti ṣe ọpọ atunṣe si iwe ofin naa, sibẹ ko ti i le yanju awọn ipenija orilẹ-ede yii. Fun idi eyi, o ṣe pataki ki wọn ṣe tuntun dipo ṣiṣe atunse miiran si i.

Olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ ninu Ile, Aṣofin Sanai Agunbiade sọ pe sọ pe ẹsẹ oṣelu tiwantiwa ko ti i fẹsẹ mulẹ ni orilẹ-ede yii, nitori aisi ijọba apapọ tootọ. Eleyii lo si n ṣokunfa ifẹhonuhan awọn ara ilu ti wọn n beere fu yiyapa kuro lara orilẹ-ede Naijiria. O ni ṣiṣe atunṣe kikun si iwe ofin lo le yanju iru awọn aawọ bayii.

Ọpọ ninu awọn aṣofin ninu Ile Aṣofin yii ni wọn fi awijare wọn ṣatilẹyin fun erongba yii. Lara eyi ni wọn ti beere fun fifun awọn ijọba ipinlẹ lagbara lati da ile-iṣẹ ọlọpaa ti wọn silẹ. Omiran ni bibu ẹnu atẹ lu bi awọn agbofinro ṣe kọlu awọn afẹhonuhan ninu ayajọ ijọba tiwantiwa yii, pe igbesẹ wọn ba ofin mu.

Ẹwẹ, Agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa sọ pe nitoootọ, o tọ ki a ṣajọyọ ayajọ ijọba tiwantiwa to fẹsẹ mulẹ lati ọdun mejilelogun sẹyin, eleyii to fun awọn ara ilu lẹtọọ lati yan awọn ti wọn fẹ sipo.  O ni:

“A gbọdọ gboriyin fun awọn to ti ja fun ijọba awaarawa yii, ti ọpọ ti padanu ẹmi wọn sinu ija yii. A si gbọdọ gboriyin fun akitiyan aarẹ fun aṣẹ aarẹ ipele kẹwaa ti o fi kede ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun fun isaami ijọba tiwantiwa yii. A si ni lati ki Ile Igbimọ Aṣofin Apapọ fun akitiyan wọn lati fẹsẹ ijọba tiwantiwa yii mulẹ.

Sibẹ, a si ni ọpọ nnkan lati ṣe ki ijọba tiwantiwa yii le tẹ siwaju. Awọn to yan wa sipo, wọn ni ẹtọ lati lati fi ẹdun ọkan wọn han. Ko boju mu bi wọn ko ṣe jẹ ki awọn eniyan fẹhonu han ni aṣiko ayajọ ijọba tiwantiwa to kọja. Aarẹ funrare ṣaa fẹhonu han ko to dori aleefa. Bakan naa la a o maa pe fun ṣiṣe idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ. Bakan naa ni ṣiṣe atunto iṣakoso ijọba ṣe pataki. O si yẹ ki ijọba apapọ o ba awọn ikọ ti wọn n pe fun ominira ẹkun wọn bii ikọ “Biafran ati Oduduwa” jiroro, ki i ṣe nipa ipa nikan ni wọn le fi yanju iṣoro naa.”

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.