Take a fresh look at your lifestyle.

A ó túbọ̀ fẹsẹ̀ ètò ìjọba tiwa-n-tiwa múlẹ̀ ní ẹkùn wa- Àjọ ilẹ̀ ECOWAS

Ademọla Adepọju

67

Àjọ ilẹ̀ Afirika tí a mọ̀ sí, Economic Community of West African States, (ECOWAS) ti fẹnukò láti rí i pé wọ́n fẹsẹ̀ ètò ìjọba tiwa-n-tiwa múlẹ̀ ní ẹkùn wọn nípa gbígbárùkù ti  ètò ìdìbò tó múná dóko ní ẹkùn oníkálukú wọn.

Alaga  ajọ ECOWAS  ati aarẹ orilẹ ede  Ghana, Nana Akofo-Addo lo sọ eleyii lasiko ti wọn bẹrẹ ipade  awọn aarẹ ati adari  orilẹ ede  to waye ni  Accra, Ghana.

Nana Akofo wa lo anfaani naa lati dupẹ  lọwọ gbogbo orilẹ ede Afirika  fun atilẹyin ti wọn se fun  oludije  lati orilẹ ede Ghana  ti wọn dibo fun gẹgẹ bi ọkan lara  igbimọ ajọ agbaye

Aarẹ Nana Akufo-Addo,  wa tun beere fun ifọwọsowọpọ gbogbo orilẹ ede Afirika lati mu eto idagbasoke ba ẹkun wọn.

O tun wa dupẹ lọwọ gbogbo orilẹ ede  Afirika fun igbiyanju wọn lati mu eto ijọba tiwa-n-tiwa  gbilẹ , o tun wa lo anfaani ọhun lati ki aarẹ orilẹ ede Niger ati Benin ku ori ire fun bi wọn se jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ  ninu eto idibo to waye lorilẹ ede wọn.

ÈTÒ  ÀTÚNSE NÍ ÀJỌ ÀGBÁYÉ
Aarẹ  Akufo-Addo wa rọ ajọ UN lati satunse to mọnyan lori nipa yiyan  awọn asoju ilẹ Afirika sinu igbimọ ajọ agbaye.

O tun wa bẹnu atẹ lu iwa ọlọtẹ, iwa ipaniyan ati aarun COVID-19 ti o jẹ ipenija fun eto idagbasoke ilẹ  Afrika.

ÀTÌLẸ́YÌN ÀJỌ ÀGBÁYÉ (UN )
Ninu ọ̀rọ̀ tirẹ , asoju ọfisi akọwe agba fun ajọ UN , Sahel, Annadif Saleh,naa tun sọ pe ajọ agbaye ti seleri lati ran ajọ ilẹ ECOWAS lọwọ lati ri i pe eto ijọba tiwa-n-tiwa  fẹsẹ mulẹ ni orilẹ ede Mali,. Bakan naa ni ajọ agbaye tun nifẹẹ si eto idagbasoke eto ijoba tiwa-n-tiwa to bẹrẹ ni orilẹ ede  Cote D’Ivoire ati Cape Verde.

Akinwumi Adesina naa wa dupẹ lọwọ aarẹ Muhammadu Buahri ati awọn adari orilẹ ede  Afrika fun atilẹyin ti wọn se fun un lati di dibo yan an gẹgẹ bi aarẹ ile-ifowopamọ ti ajọ Afirika, African Development Bank. AfDB ,ni ẹẹkeji.

ÌPÈNÍJÀ LÓRÍ ÈTÒ ÀÀBÒ
Adesina  wa rọ gbogbo ilẹ Afirika  lati mojuto eto aabo ni ẹkun wọn , ni eyi ti o jẹ idiwọ fun eto idagbasoke okoowo.

Akọwe agba fun  awọn orilẹ ede Faranse , Louise Mushikwiwabo  naa tun sọ pe orilẹ ede wọn yoo se atilẹyin fun ajọ ECOWAS lati da eto ijọba tiwa-n-tiwa padà ni orilẹ ede  Mali.

Aarẹ orilẹ ede Naijiria tẹlẹri, Goodluck Jonathan, ti o jẹ ẹni to n soju ajọ  ECOWAS lati pẹtu si wahala to n sẹlẹ ni orilẹ ede Mali, naa tun  salaye fun ajọ ECOWAS nipa idagbasoke ti o n sẹlẹ lori eto ijọba tiwa-n-tiwa ni orilẹ ede  Mali.

Leave A Reply

Your email address will not be published.