Take a fresh look at your lifestyle.

Nàíjíríà yóò dá kíkó suga láti òkè òkun dúró láìpẹ́-Mohammed Sabo

Ademọla Adepọju

117

Mínísítà fún ètò ọ̀gbìn lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà ,Mohammed Sabo ti ní orílẹ̀ èdè Nàíjíríà kò ní pẹ́ dá kíkó suga láti òkè òkun dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni ìjọba yóò pèse ibi tí àwọn daran-daran yóò gbé máa sin àwọn ẹranko wọn.

Minisita sọrọ yii nibi ifilọlẹ ipade igbimọ eto ọgbin ati idagbasoke igberiko , eyi ti o jẹ ikẹrinlelogoji rẹ , ti wọn se niluu Abuja , ni eyi ti wọn pe akọle rẹ ni ‘Pipese ounjẹ lopọ janturu lorilẹ ede Naijiria  laarin idojukọ aarun  COVID-19, OMÍYALÉ ÀTI ÀÌNÍ ÈTÒ ÀÀBÒ TÓ PÉYE.’

Minisita tun tẹsiwaju pe aarun Corona , omiyale ati aini eto aabo to peye lorilẹ ede Naijiria , tun ran ijọba lọwọ lati pese awọn ohun amayedẹrun , ohun elo igbalode , irinsẹ ọgbin ati  lati mu idagbasoke ba eto ọbin lorilẹ ede Naijiria.

minista tun sọ pe ijọba tun  ti fọwọsowọpọ pẹlu ile isẹ Fundacao Getulio Vargas (FGV)  to wa ni orilẹ Brazil lori eto ọgbin nipa yiya owo to din ni ẹgbẹrun kan  miliọnu pọnsi  €995m,owo ilẹ okeere fun idagbasoke eto ọgbin lorilẹ ede Naijria.

Minisita ipinlẹ fun eto ọgbin lorilẹ ede Naijiria,Mustapha Shehuri  tun sọ pe awọn tọrọ kan lori eto ọgbin naa tun gbọdọ fọwọsowọpọ lati gbe eto ọgbin larugẹ lorilẹ ede Naijiria.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.