Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò ààbò tó mẹ́hẹ: Ààrẹ Buhari sèlérí láti dá ètò ààbò padà sí Borno

122

Ààrẹ  Muhammadu Buhari  ti fọkàn  gbogbo àwọn tó ń gbé ní ipinlẹ Borno  balẹ̀ pé ohun kò ní  dáwọ́ gbígbógun ti gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ tó ń da omi àlàáfíà ìlú náà rú , bákan náà, ni ìjọba yóò rí i pé gbogbo àwọn tí ogun lé kúrò nílùú wọn ní yóò padà sí ìlú wọn ni àlàáfíà.

Aarẹ wa tun lo anfaani naa lati tun gbosuba fun gomina ipinlẹ Borno,Babagana Umara Zulum  fun akitiyan rẹ lati mu idagbasoke ba ipinlẹ Borno.

Aarẹ Buhari,  lọ si ipinlẹ  Borno nitori eto aabo ni ipinlẹ ọhun ati lati tun lọ ṣe awọn ifilọlẹ ohun amayedẹrun ti gomina pese ni ipinlẹ naa.Aarẹ tun wa ni ipinlẹ Borno lati tun gbosuba fun ikọ ọmọ ogun orilẹ ede yii fun aseyọri ti wọn se ni ipinlẹ naa paapaa julọ ni  Dikwa, Damboa ati Gwoza.

“Inu mi dun lati wa ni ipinlẹ Borno lẹẹkan si .Mo mu ipinlẹ Maiduguri ati Borno gẹgẹ bi ile mi, nitori pe mo ti jẹ gomina ni awọn ipinlẹ yii rí ,lasiko ti mo jẹ ologun  ni ọdun mẹrindinlaadọta ṣeyin.

Aarẹ tun gbosuba fun awọn akinkanju ikọ ọmọ ogun orilẹ ede yii ati awọn ọdọ ti wọn farajin lati fẹmi wọn lelẹ fun alaafia ilu ati orilẹ ede wọn.Nitori iwa akinkanju yii, ti wọn seni ijọba se gba pupọ ninu awọn ọdọ ipinlẹ yii si ile-isẹ ọmọ ogun .

Ipese ina mọna-mọna

Aare ni ijọba oun ko ni kaarẹ lati pese ina mọna-mọna  fun gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria ati pe ilu Maiduguri yoo jẹ ninu anfaani yii.

Aarẹ tun wa lo anfaani yii lati gbosuba  fun gomina ipinlẹ Borno fun gudugudu meje , yaya mẹfa ti o ti pese ni ipinlẹ naa lati mu igbe aye irọrun fun awọn ara ilu, nipa pipese isẹ́, ohun amayedẹrun ati awọn ohun amayedẹrun miran.Aarẹ tun tẹsiwaju pe:

“Mo tun dupẹ lọwọ Shehu ti Borno, ati  gbogbo awọn ọba  ati awọn Bulama ni gbogbo ipele fun iwa akinkanju , suuru, ati ọgbọ́n ti wọn lo lati igba ti awọn olọtẹ  ati odaran ti n da wọn laamu.”

“ Mo tun dupẹ lọwọ awọn agba ilu, awọn asiwaju,Musulumi, onigbagbọ, awọn adari  ilu ni ipinlẹ yii  fun iwa asiwaju ati iranlọwọ ti wọn n se fun ijọba apapọ ati ipinlẹ lasiko ipeniya yii.

“Bakan naa, ni mi o tun ni gbagbe pe ipinlẹ Borno  ni mo ti ri ìbò to pọju lasiko ti mo n dije fun ipo aarẹ orilẹ ede yii, nitori naa ,mi o ni kaarẹ lati ri i pe eto alaafia jọba ni ipinlẹ Borno ati ni orilẹ ede Naijiria.”

Gomina ipinlẹ Borno, Zulum naa wa dupẹ lọwọ aarẹ fun gbogbo igbiyanju ati iranwọ rẹ lati pese eto alaafia ni ipinlẹ naa ati bi aarẹ se pese awọn ikọ ọmọ ogun ati awọn agbofinro ti wọn ti n koju ija ṣi awọn ọlọtẹ ni ipinlẹ naa.O tẹsiwaju pe

“Alaafia ti n jọba ni ipinlẹ Borno, a si ni igbagbọ pe gbogbo awọn ọlọtẹ ati ọdaran ni yoo  di ohun igbagbe. ” .

Gomina tun wa dupẹ lọwọ aarẹ bi o se fọwọsi ile-ẹkọ gbogbonse to wa ni Mongonu lẹyin ogoji  ọdun ti wọn to da ipinlẹ naa silẹ lọdun 1976.Gomina tun wa bẹ̀bẹ̀ fun ikọ ọmọ  ogun ni ipinlẹ naa lati pese eto aabo to peye .

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.