Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-iṣẹ́ tí ó ń risí ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ NCC bẹ̀rẹ̀ àtúnyẹ̀wò ìlànà láti gba ìwé-àṣẹ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

136

Ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ètò  ìbáraẹnisọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, (NCC) ti bẹ̀rẹ̀ ìlànà fún àtúnyẹ̀wò gbígbà ìwé-àṣẹ láti dá irú ilé-iṣẹ́ ọ̀hún sílẹ̀, tí ó wà tẹ́lẹ̀ fún ilé-iṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti orílẹ̀-èdè.

Eleyi pan dandan nitori ibi taye darisi ati bi olọkanọjọkan ọna ibaraẹnisọrọ  amayedẹrun ṣe n gbooro si.

Ilana to mu aṣeyọri    yii bẹrẹ nigbati igbakeji alaga alakoso,NCC,Ọjọgbọn Umar Danbatta ṣe ifilọlẹ igbimọ inu ile kan lati  ṣe iṣẹ naa.

O sọ pe, awọn idagbasoke ti ba eto ibaraẹnisọrọ kariaye,ati pe a n ri bi ipa ribiribi  ti o nko ṣe npọ si ni orilẹ-ede Naijiria.

 

Gẹgẹbi alaye kan lati ẹnu  Oludari, ọrọ iṣe gbogbogboo, NCC, Dokita Ikechukwu Adinde, oludari NCC,pe akiyesi si  pe ilana iwe-aṣẹ wọn n lo lọwọlọwọ bayii ti fẹrẹ to ogun ọdun , nitorinaa  atunyẹwo ilana rẹ kiakia ṣe pataki.

O sọ pe eyi yoo ṣe afihan  awọn  aṣa iwe-aṣẹ tuntun ni ila pẹlu ti agbaye, ti yoo si tun jẹ ọna ati pawo wọle fun ijọba.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.