Àwọn ènìyàn mẹ́tàdín-lógún míràn tún ti ní ààrùn covid ní Nàìjíríà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé-iṣẹ́ tí ó ń ṣàmójútó àjàkálẹ̀ ààrùn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NCDC ti sọ pé, ènìyàn mẹ́tàdín-lógún míràn ló tún ti ní ààrùn covid báyìí o,ìyẹn ní ọjọ́ ìṣẹ́gun.
NCDC sọ eyi di mimọ nipasẹ oju opo wẹẹbu rẹ ni Ọjọbọ.
O ṣalaye pe, ko si ẹnikankan to ni aarun ọhun ni ipinlẹ mọkanla;Plateau,Nasarawa, Cross River,Imo,Kano, Bauchi,Kaduna, Sokoto,Oyo, Ondo ati Ekiti.
Gẹgẹ bii ile-iṣẹ ọhun ṣe sọ,mẹtala ninu mẹtadin-logun eniyan ọhun wa lati Lagos,Gombe-ẹyọkan ti mẹta si jẹyọ ni Rivers.
NCDC ṣe akiyesi pe , awọn eniyan ọ̀kẹ́ mọ̀kan-le-ni-àádọ́fà o le ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbàfà o le ni ẹ̀sán le ni irinwó ni wọn ti ṣe ayẹwo fun lati igba ti aarun covid ti kọkọ jẹyọ ni ọjọ kẹtadin-lọgbọn, oṣu keji ọdun 2020
NCDC sọ pe,awọn eniyan ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin le ni ọ̀kẹ́ mẹ̀jọ o le ni àrún din ni ọgọ́rùn lo ti ni aarun naa lọwọlọwọ bayii,ti ẹgbẹ́ẹ́ẹdógún le ni ọ̀kẹ́ mẹ̀jọ o le ni eétàdínlógún din ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta si ti gbawosan.
O ṣafikun pe,ko si enikankan to ku ni bii wakati mẹrinle-logun sẹyin.
Leave a Reply