Take a fresh look at your lifestyle.

Bi a se le fẹsẹ oṣelu Tiwa-n-tiwa mulẹ ni Naijiria- Aṣofin Ọbasa

29

Lanre Lagada-Abayomi

Eleyii ni ọrọ Agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ajayi Ọbasa lati fi saami Ayajọ Ijọba Tiwa-n-tiwa orilẹ-ede Naijiria fun tọdun 2021:

“Bi a n ṣe n saami ayajọ ijọba Tiwa-n-tiwa ti ọdun 2021 yii, o yẹ ki a mọ pe orilẹ-ede Naijiria ti lanfani ati fi ẹsẹ ijọba awaarawa yii mulẹ lati bii ọdun mejilelogun sẹyin. Eyi fi han pe awọn ọmọ orilẹ-ede yii ti pinnu ati fi ijọba ti awọn ara ilu yoo le fi ẹdun ọkan wọn han, ti ko ni soju ṣaaju lelẹ, eleyii ti ko ri bẹẹ ninu saa ijọba ologun.

Ni pẹki-n-pẹki, oni yii naa la n ṣajọyọ ọdun mejidinlọgbọn eto idibo ti to gbe Oloye M.K.O Baṣọrun wọle gẹgẹ bi aarẹ nigba naa ni ọdun 1993, bi wọn ko tilẹ gbe ipo naa fun.

Fun pe orilẹ-ede yii si wa ni iṣokan pẹlu gbogbo ipenija ati aawọ ẹlẹyamẹya to n waye laarin ara wa, eleyii fi han pe ifẹ wa laarin wa ati awọn ẹlẹya miiran to wa laarin wa, gẹgẹ bi ọmọ orilẹ-ede Naijiria.

Orilẹ-ede Naijiria ti wa lojuna ilọsiwaju. A si ti ri ipenija lorisirisi pẹlu awọn iṣakoso ijọba to koja, ka to pinnu lati fara mọ eto oṣelu tiwa-n-tiwa, gẹgẹ bi eleyii to dara ju. Fun idi eyi, gbogbo wa lẹnikọọkan ati lapapọ lo lojuṣe lati ṣiṣẹ lojuna ati fẹsẹ ijọba tiwa-n-tiwa yii mulẹ fun anfani ara wa ati torilẹ-ede yii lapapọ.

Gbogbo wa gbọdọ kẹyin si awọn igbesẹ to tako ilosiwaju orilẹ-ede yii. Dipo eyi, a gbọdọ figagbaga fun ohun ti yoo mu ilosiwaju ba wa. Ki gbogbo wa ni igbagbọ pe nnkan yoo dara ni orilẹ-ede yii. Ki a mọ pe a ko ni ibomiran ju orilẹ-ede yii lọ. Ati alaṣẹ, ati awọn ara ilu ki a fara jin fun orilẹ-ede yii, ki a si yago fun awọn ipenija ati awọn iwa to to le ṣakoba fun eto aabo ilu.

Mo dupẹ lọwọ awọn olori wa, bii Aṣiwaju Ahmed Bọla Tinubu ti wọn fara ja fun ominira lọwọ ijọba ologun, lati fẹsẹ ijọba tiwa-n-tiwa mulẹ lorilẹ-ede yii.

Mo tun ki awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ati awọn olugbe Ipinlẹ Eko ku oriire. Ipinlẹ ti o n jẹ aṣiwaju ninu aṣeyọri pẹlu iṣẹ takuntakun ijọba lati mu ilu rọrun fun awọn eniyan lati gbe.

Ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, a ti ti ṣe ofin ati ifẹnuko loriṣiriṣi fun igbe aye irọrun awọn ara ilu. A ko si ni kaarẹ ninu eyi, lati le jẹ ki ipinlẹ yii wa niwaju.”

Aṣofin Mudashiru Ọbasa

Agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinle Eko         

Leave A Reply

Your email address will not be published.