Take a fresh look at your lifestyle.

Awọn alenulọrọ lEko beere fun ṣiṣe atunṣe si ofin sisan owo ifẹyiti fun awọn Gomina, Igbakeji Gomina

196

Ipade Ita-gbangba to da lori ṣiṣe ayipada ofin to fun awọn alaṣẹ tẹlẹ bi Gomina ati igbakeji rẹ lanfani si awọn ẹtọ ajẹmọnu kan, eleyii ti Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ṣe. Ẹwẹ, awọn alẹnulọrọ beere pe ki wọn ṣe atunṣe si ofin naa dipo ki wọn yọ ọ kuro patapata.

Abadofin tuntun naa ni wọn pe akori rẹ ni: “Abadofin Ṣiṣe ayipada ofin to pese fun sisan owo-ifẹyinti fun alaṣẹ ijọba ti wọn ti kuro nipo ni Ipinlẹ Eko ati awọn ohun miiran to jẹ mọ ọn.” Eleyii lo waye ni gbagede Ile Igbimọ Aṣofin naa ni ilu Ikeja.

Ofin tẹlẹ naa fun awọn Gomina ati Igbakeji Gomina tẹlẹ lanfani si owo-ifẹyinti to ṣe deedee si ojulowo owo oṣu ti Gomina ati Igbakeji to wa lori oye lọwọlọwọ n gba ati awọn ohun ajẹmọnu miiran gẹgẹ bi Ajọ to n Ṣamojuto Owo to n wọle si apo Ijọba ati Ṣisamulo Owo Ilu, ṣe fi lelẹ. Bakan naa ni ofin naa tun fi mulẹ pe Gomina tẹlẹ naa ati igbakeji rẹ yoo lanfani si ile gbigbe nibikibi to ba wu wọn ni agbegbe Ipinlẹ Eko.

Bakan naa, Gomina to ba lo saa meji lori aleefa yoo lanfani si ile miiran ni agbegbe Abuja, ti i ṣe olu-ilu orilẹ-ede Naijiria.

Ni ti ọkọ, ofin naa fun awọn Gomina bayii lanfani si ọkọ ayọkẹlẹ meji, pẹlu awakọ kan, ati alekun ọkọ ayọkẹlẹ miiran, ti wọn yoo maa paarọ wọn lọdọọdun. Bẹẹ ni wọn yoo maa sanwo ifẹyinti fun awọn awakọ wọn naa bi wọn ba fẹyinti.

Ni ti ipese aabo, Gomina tẹlẹ ni anfani si awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ meji ti yoo maa ba a ṣiṣẹ, pẹlu ojulowo ọlọpaa mejọ. Mẹfa yoo maa ṣiṣẹ pẹlu Gomina tẹlẹ naa, nigba ti meji yooku yoo maa ba Igbakeji Gomina naa ṣiṣẹ.

Ninu ọrọ Akowe Ẹgbẹ Awọn Onimọ Ofin lorilẹ-ede Naijiria, ẹka ti Ikeja, Ogbẹni Adeyẹmi Abijo lori abadofin tuntun yii, o gboriyin fun igbesẹ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko fun Igbesẹ yii. O ni ofin tẹlẹ naa ti fun awọn gomina ana ni anfani to pọ ju, ati pe eyi ti wọn n fun wọn naa ti pọ ju ọrọ owo-ifẹyiti lasan lọ, paapaa ni asiko yii ti awọn ara ilu n koju ọrọ-aje to dẹnu kọlẹ yii.

Ẹwẹ, Ogbẹni Abijo wa sọ pe dipo ki wọn fagi le ofin naa, ki wọn si maa fun wọn ni owo ifẹyinti diẹdiẹ, gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe ni awọn orilẹ-ede nla, bi orilẹ-ede Amẹrica, ki ijọba si lo awọn owo rẹpẹtẹ ti wọn n fun wọn yii sori inawo ilu miiran.

Akọwe Ẹgbẹ Ajafẹtọ-ọmọniyan kan, iyẹn Defence of Human Rights, ẹka ti Ikẹja, Ọgbẹni Ayọdele Mustapha sọ pe o yẹ ki awọn olori yii rira wọn bi ẹni ti o sin ilu ni, ko yẹ ki wọn tun maa gba owo rẹpetẹ bayii.

Ẹwẹ, oun naa beere pe ki ijọba si fi awọn ẹtọ ajẹmọnu to nii ṣe pẹlu itọju ara, awọn awakọ ati awọn ẹṣọ alaabo fun awọn gomina tẹlẹ ati igbakeji wọn silẹ.

Ṣaaju eyi, ninu ọrọ ikini kaabọ rẹ, Alaga Igbimọ to n moju to ọrọ Ile-iṣẹ ijoba, Idanilẹkọọ, ẹtọ ajẹmọnu ifẹyinti ati Iṣẹ ijọba lapapọ, ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Oluyinka Ogundimu sọ pe ipade-ita-gangba naa je ara igbesẹ ti Ile naa ni lati gbe fun abadofin bayii.

Aṣofin Ogundimu sọ fun awọn oniroyin pe gbogbo aba awọn ara ilu ni awọn maa gbe yẹwo lori abadofin yii.

Agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin naa, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, ẹni ti Igbakeji rẹ, Aṣofin Wasiu Ẹshinlokun-Sanni ṣoju fun fara mọ pe ki wọn yi ofin owo-ifẹyinti yii pada. Aṣofin Obasa gbagbọ pe pẹlu bi ọrọ-aje ko ṣe ṣẹnu ‘re bayii, wọn ni lati yi ofin naa pada, ki wọn le na iru owo bẹẹ si idagbasoke ilu.

O ni sibẹ wọn ko ni ṣaimọ riri awọn alaṣẹ tẹlẹ naa ninu ofin lati fi fẹmi imoore han si akitiyan wọn fun ilu.

Leave A Reply

Your email address will not be published.