Take a fresh look at your lifestyle.

Wọn ò pa ọmọ ogun Nàíjíríà ,a ò wá láti gbẹ̀san- Ilẹ́- isẹ́ ológun

Ademọla Adepọju

29

Ilé isẹ́ ologun ti ni ahesọ ọrọ lasan ni iroyin ti wọn n gbe kiri lori ẹrọ ayelujara pé , ikọ ọmọ ogun Naijiria wa ni ipinlẹ Abia lati gbẹsan lara awọn ara ilu nipa bi  ikọ ọlọ̀tẹ̀ ESN/IPOB se pa mẹ́fà lara ikọ  ọmọ ogun orilẹ ede yii nigba ti awọn mejeeji jọ wọ́yà  ìjà.

Ile-isẹ ọmọ ogun naa tun sọ pe irọ patapata ni pe awọn to n gbe ni  Elu, Amangwu ati Amaekpu to wa ni ijọba ibilẹ  Ohafia ti fi ilu naa silẹ nitori ibẹru.

Ile-isẹ ologun tun sọ pe ikọ ọmọ ogun orilẹ ede yii, awọn agbofinro, ile-isẹ  ọlọpaa jọ n se isẹ́ papọ, pẹlu awọn iroyin ti awọn eniyan ba fun wọn  lati ri i pe alaafia jọba ni gbogbo agbegbe ọhun.

O wa fọkan awọn ọmọ ipinlẹ Abia balẹ pe ki wọn maa se foya , pe awọn wa ni ipinlẹ naa ;lati daabo bo dukia ati ẹmi awọn ara ilu.O tun wa rọ awọn ara ilu ki wọn maa fi to eti wọn, ti wọn ba fura si awọn eniyan ibi to fẹ da omi alaafi ilu naa rú.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.