Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ mú ètò ìwòsàn àwọn ọmọ ogun Nàíjíríà ní ọ̀kúnkúndùn-Ahmad Lawan

Ademọla Adepọju

0 140

Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asòfin lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Ahmad Lawan  ti rọ àwọn adarí ilé-isẹ́ ọmọ  ogun orílẹ̀ èdè yìí láti mú ètò ìwòsàn àwọn ọmọ ogun  orílẹ̀ èdè yìí ní ọ̀kúnkúndùn, kí wọ́n sì sàtúnse tó mọ́nyán lórí sí àwọn  ilé-wòsàn ti àwọn awọn ọmọ ogun tí ó ba farapa ti ń gba ìtọ́jú.

Ahmad Lawan sọrọ yii lasiko to n se abẹwo si awọn ikọ̀ ọmọ ogun to farapa , ti wọn si n gba itọju nile iwosan to wa niluu Kaduna.O ni ile igbimọ asofin n se abẹwo yii lati sami ayẹyẹ ọdun meji ti wọn ti wa nile igbimọ asofin.

Ahmad Lawan wa seleri fun ile-isẹ ọmọ ogun naa pe ile igbimọ asofin kẹsan an yii  yoo pese eto iranwọ ti yoo lee jẹ ki wọn le se isẹ́ wọn bi isẹ́.

Ọgagun  Danjuma Ali-Keffi ti o jẹ adari ikọ ogun ti ipinlẹ kaduna naa wa gbosuba fun ile igbimọ asofin  fun abẹwo ti wọn se yii.

Adele ikọ ọmọ ogun ti o n dari ile-iwosan ti ọwọ ọmọ ogun ti ikọ kẹrinlelogoji , Steven Onuchukwu  naa tun fi ẹ̀mí imoore  han sí  ile igbimọ asofin fun abẹwo ọhun.

Lara awọn ti o tẹle abẹnugan ile igbimọ asofin fun eto abẹwo naa ni ,  Yahaya Abdulllahi, Orji Uzo Kalu, Danjuma Laah ati Abdu Kwari.

Leave A Reply

Your email address will not be published.