Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jẹ́ ká yẹra wa wò, bóyá à ń sin orílẹ̀ èdè tàbí ara wa- Gomina Ifeanyi Okowa

Ademọla Adepọju

51

Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta, Ifeanyi Okowa ti ní, òtítọ̀, ìdájọ́ òdodo àti ìwà àparò kan, kò ga ju ọ̀kan lọ,  ní gbogbo ẹkùn orílẹ̀ èdè Nàíjíríà nìkan lo lé jẹ́ kí orílẹ̀ èdè Nàíjíríà wà ní ọ̀kan.

Okowa sọrọ yii lasiko eto idupẹ lati fi sami ayẹyẹ ajọdun ọdun keji ti igbimọ asofin de ori ipọ, ni eyi ti wọn se ni ilé  ìjọsìn  Living Faith Church, Asaba.

Gomina tẹsjiwaju pe  oun ni igbagbọ ninu isọkan orilẹ ede Naijiria,awọn adari si  gbọdọ maa  se ohun gbogbo nipa ifẹ orilẹ ede .

Okowa tun sọ pe bo tilẹ jẹ pe orilẹ ede Naijiria n koju awọn ipenija orisirisi sibẹ awọn onigbagbọ gbọdọ maa tẹramọ adura fun orilẹ ede Naijiria. “nitori pe Ọlọrun nikan lo lee da orilẹ ede yii pada bọ̀ sípò.”

“ Ọpọlọpọ nnkan ni a lee kọ lára awọn ipenija ti a n la kọja.A  gbọdọ lee fọwọṣowọpọ lati ri i pe a tẹramọ idagbasoke ati isọkan orilẹ ede Naijiria.

“Ẹ má sọ igbagbọ nu, lẹyin adura ti a n gba , ẹ jẹ ka sa ipa wa gẹgẹ bi ẹnikọọkan.

Ni ọpọlọpọ igba , ni a maa n ka orin ti orilẹ-ede wa laisi akiyesi awọn ọrọ inu rẹ. A le sin orilẹ-ede wa l’otitọ pẹlu ifẹ ati okun bi a ba gbagbọ ninu iṣọkan orilẹ-ede naa.

“ Ọpọlọpọ  awọn eniyan lo ti n  pariwo fun  eto  atunṣe ati ijiroro nipa  orilẹ-ede nitori awọn ohun ti a n rii, ṣugbọn a gbọdọ tẹsiwaju ninu isọkan  orilẹ-ede wa; o daju pe, a o ni   ayipada to dara laipẹ.” .

Gomina  wa gbosuba  fun igbimọ asofin  ipinlẹ  fun ifowọsowọpọ pẹlu ijọba rẹ

Saaju eyi ni, alufaa David Popoola ti ṣe iwaasu rẹ lori ohun ti o pe akori rẹ ni : “ Nini oye nipa awọn isẹ́ iyanu nipa idupẹ’’ Pasitọ David Popoola wa rọ awọn onigbagbo lati maa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ibukun rẹ lori igbe ayé wa.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.