Take a fresh look at your lifestyle.

Ogúnlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn fẹ̀hónúhàn fún pípa àwọn mùsùlùmí mẹ́rin ní London

Ademọla Adepọju

44

Ogúnlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ni wọn ti tú jáde lọ́jọ́ Ẹti láti  fẹ̀hónúhàn fún  bi ọkùnrin kan se fi ọkọ̀ pa  àwọn  ọmọ orílẹ̀ èdè Canada ti wọ́n jẹ́ mùsùlùmí lọ́jọ́ Àìkú, ni eyi ti awọn ọlọ́pàá pè ní ìwà ìpànìyàn.

Awọn eniyan mẹrin  yii sagbako ijamba ọkọ  nigba ti Nathaniel Veltman,ọmọ ogún ọdun  20,fi ọkọ rẹ pa  awọn eniyan wọnyi lasiko ti wọn n rin ni irọlẹ lọ si ilé wọn, ẹni karun un ninu wọn ti o jẹ ọmọ ọdun mẹsan an  to wa ninu ọkọ naa nikan ni ó yè ninu awọn eniyan naa.

Awọn eniyan to wa ni ilu London, Ontario ni wọn bẹrẹ ifẹhonuhan wọn ni ọgangan ibi ti ọkọ ti pa awọn eniyan ọhun , ti ko jinna si mọsalasi ti wọn ti n kirun, ki to di pe ọwọ ọlọpaa tẹ ọkunrin , ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe Veltman ti farahan nile ẹjọ́ lọjọBọ  fún ẹ̀sùn ipaniyan sugbọn yoo tun pada lọ sile ẹjọ ni ọjọ Aje to n bọ yii.

Adari ijọba orilẹ ede Canada, Justin Trudeau ti sọ pe ẹsun ipanian gbaa ni iru ẹsun bayii.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.