Take a fresh look at your lifestyle.

Twitter ti ń pàdánù ọ̀kẹ́àìmọye owó, wọ́n fẹ́ bá ìjọba jíròrò papọ̀- Lai Mohammed

Ademọla Adepọju

84

Mínísítà fún ètò ìròyìn àti àsà  lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà.,  Lai Mohammed,ti ní olùdarí ìtàkùn  ẹ̀rọ̀ ayélujára  Twitter,  ti fẹ́ bá ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà jíròrò láti yanjú ìsoro tó  jẹ́ kí  ìjọba  dá àwọn isẹ́ rẹ̀ dúró lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà.

Mohammed  sọrọ yii lasiko ti o  n ba awọn akọrọyin ile aarẹ sọrọ niluu Abuja, lẹyin ipade igbimọ ijọba ti wọn se , ni eyi ti aarẹ Muhammadu Buhari dari rè.

O tẹsiwaju pe  ki itakun Twitter to tun le pada bẹrẹ isé lorilẹ ede Naijiria, o gbodo forukọ silẹ pẹlu ajo to n mojuto  eto iforukosilẹ awọn ile isẹ́ lorilẹ ede Naijiria, iyẹn Nigerian Corporate Affairs Commission, ki wọn si gba  iwé àsẹ lati fi bẹrẹ isẹ́ wọn.

Lai, ni ki i ṣe  itakun Twitter nikan ni yoo fukọsilẹ lati gba iwe asẹ, lati bẹrẹ isẹ lorilẹ ede yii, koda  itakun ẹrọ ayelujara bii Facebook ati  Instagram  naa yoo forukọsilẹ fun iwe àsẹ lati bẹrẹ isẹ wọn.

Minisita tun tẹsiwaju pe   awọn kò tàpá si ofin ẹ̀tọ́ awọn eniyan lati lee sọrọ nipa bi wọn se da itakun Twitter  duro, sugbọn awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria si lee maa lo itakun ẹrọ ayelujara  Facebook ati Instagram.

Lai, tun tẹsiwaju pe awọn da itakun ẹrọ ayelujara Twitter duro nipa iwa ti wọn n hu  lati dá wahala silẹ lorilẹ ede Naijira ati pe oludasilẹ ile-isẹ Twitter Jack Dorsey,tun ran awọn ajijagbara #EndSARS lọwọ lati fun wọn lówó lasiko ifẹhonuhan, bakan naa, ni o gba  oludari  ẹgbẹ, Indigenous People of Biafra (IPOB), Nnamdi Kanu,laaye lati maa lo  ìtàkùn  ẹrọ ayelujara Twitter  fun iwa ipaniyan lati maa pa awọn agbofinro , ti wọn si tun n dana sun awọn ile-isẹ́ ijọba.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.