Take a fresh look at your lifestyle.

Òfin láti máa pa ẹnikẹ́́ni tó bá gbé ìbọn AK47 lọ́wọ́, sì wà síbẹ̀

Ademọla Adepọju

133

Ààrẹ orilẹ ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti tun tẹpẹlẹ mọ àsẹ tó pa fún àwọn agbófinro àti ilé-isẹ́ ọmọ ogun láti máa yì̀nbọn pa ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí ìbọn AK-47 lowọ́ rẹ̀ láì gbàsẹ lọ́wọ́ ìjọba.

Aarẹ tun seleri pe ijọba rẹ ko ni foju ire wo ‘‘ gbogbo awọn to n dana sun ile-isẹ ijọba ti wọn si tun n pa  awon osisẹ alaabo ati awon agbofinro..’’

Aarẹ sọrọ yii niluu Eko lasiko ti o lọ se ifilọlẹ  awon ohun irinsẹ eto aabo ti gomina ipinlẹ Eko ,Babajide Sanwo-Olu rà fun awon osisẹ eleto aabo.

Aarẹ tun so pe ‘‘Gẹgẹ bi adari gbogbo ọmọ ogun orilẹ ede yii, ojuse mi ni lati ri i pe eto aabo fẹsẹ mulẹ lorilẹ ede Naijria, ki gbogbo awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria lee fẹ̀dọ̀ lé orí òróǹro wọn. Bo tilẹ jẹ pe a n koju awọn ipenija to pọ bayii, sibẹ , mo fẹ ki gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria nigbagbọ pe , eto aabo yoo pada si orilẹ ede yii.”

Aare tun sọ fun gbogbo awọn agbofinro pe , ijọba n sa ipa rẹ lati mu igbaye-gbadun wọn rọrun, bi awọn ara ilu naa se n fẹ nnkna lati ọdọ ijọba.

‘‘Lakọọkọ, mo fẹ gbosuba fun adari ile-isẹ olọpaa ati awọn ikọ rẹ fun akitiyan rẹ lati mu eto aabo pada si orilẹ ede yii .‘‘

Aarẹ tun gbosuba fun gomina ipinlẹ Eko fun  gudugudu meje , yaya mefa rẹ  lati seto awọn ohun amayedẹrun si ilu Eko , laiwo ohun ti awọn endsars bajẹ lasiko ifẹhonuhan wọn.

Aarẹ ọpọlọpọ atunse ni awọn ti ṣe si ofin orilẹ ede yii lati mu igbaye dẹrun ba awọn ọlọpaa ati ara ilu.Aarẹ tun ni baayi ẹgbẹrun mẹwaa awọn ọlọpaa ni awọn n gba bayii lati tubọ pese eto aabo lorilẹ ede yii.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.