Take a fresh look at your lifestyle.

Àyípadà rere kò ní pẹ́ dé bá ètò ààbò lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà-Bashir Magashi

Ademọla Adepọju

81

Lọ́jọ́ Ajé yìí ni ààrẹ  Muhammadu Buhari ṣe ìpàdé pẹ̀lú ,adarí ilé-isẹ́ ọmọ ogun orìlẹ̀ èdè Nàíjíríà , ọ̀gágun Farouk Yahaya ,minisita fún ètò ààbò  lórílẹ̀ èdè yìí, Bashir Magashi àti adarí ilé-isẹ́ tó ń mójútó ètò ààbò , ọgagun Lucky Irabo.

Lasiko ti minisita to n mojuto eto aabo n ba awọn akọroyin sọrọ nile aarẹ to wa niluu Abuja pe, oun lo asiko naa lati mú adari ile-isẹ ikọ ọmọ ogun orilẹ ede yii wa si ọ̀dọ̀ aarẹ  

Minista tẹsiwaju pe, aarẹ sọ nipa irir rẹ fun wọn , ni eyi ti yoo wulo fun  wọn lati dojukọ awọn ipenija to wa lori eto aabo lorilẹ ede Naijiria.

O tun sọ pe, ki gbogbo awọn adari ile-isẹ to n mojuto eto aabo fọwọsowọpọ lati wa ojutuu si awọn ipenija to n dojukọ eto aabo lorilẹ ede Naijiria.

Magash wa seleri lati tubọ fọwọsowọpọ pẹlu ile-isẹ ọlọpaa lọna ati mojuto eto aabo lorilẹ ede yii.

Leave A Reply

Your email address will not be published.