Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé ìgbìmọ aṣòfin Èkó fìwé ìfèhónú-hàn àwọn ajàfẹ́tọ̀-ọ́mọnìyàn ṣọ́wọ́ sí ìjọba àpapọ̀ àti Ilé Aṣòfin Àpapọ̀

Lagada Abayọmi

0 233

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti ṣe ileri ati fi iwe ifẹhonu-han awọn ajafẹtọ-ọmọniyan ṣowọ si ijọba apapọ lati jiroro le e lori. Eyi ni ifẹhun-han ọlọjọ kan ti igbimọ awọn ajafẹtọ-ilu ṣe lati fẹdun ọkan wọn han si bi nnkan ko ṣe bojumu kaakiri orilẹ-ede Naijiria, eleyii ti wọn gbe wa si gbagede Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko.
Ninu ijiroro Ile naa, agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin yii, Aṣofin Mudashiru Ọbasa paṣe pe ki wọn fi iwe ifẹhonu-han naa ṣọwọ si Ijọba Apapọ ati Ile Igbimọ Aṣofin Apapọ. O ni:
“Ile Igbimọ Aṣofin yii ni agbenusọ fun awọn ara ilu ni Ipinlẹ Eko. Ki iru ọrọ bayii lọ sọdọ Aarẹ. Awa naa yoo si foju sunnukun wo awọn ọrọ to ba jẹ ti wa nibi. A o ran wọn lọwọ lati fi iwe ẹdun ọkan wọn ranṣẹ si Aarẹ ati Ile Igbimọ Aṣofin Apapọ.”
Ẹwẹ, Agbẹnusọ Ile naa gboriyin fun igbimọ awọn ajafẹtọ-ilu naa fun ifẹhonu-han naa ti wọn ṣe wọọrọwọ. Aṣofin Ọbasa woye pe Ile Igbimọ Aṣofin naa ti fohun ṣọkan pẹlu awọn ara ilu pe ki ijọba apapọ tete wa ọna abayọ si rukerudo orilẹ-ede yii. O wa rọ igbimọ ajafẹtọ-ọmọniyan naa lati foju inu wo idagbasoke to n de ba Ipinlẹ Eko bayii
Ṣaaju eyi, Aṣofin Sanni Ọkanlawọ̣n fi to awọn akẹgbẹ rẹ ninu ijroro ile naa leti nipa ifẹhonu-han naa. O ni ifẹhonu-han ti wọn fi akori rẹ pe “Idaro Ọlọjọ kan fun Orilẹ-ede Naijiria” ni awọn ajafẹtọ-ọmọniyan naa fi fẹdun ọkan wọn han lori bi ilu ko ṣe rọgbọ rara. O ni Igbakeji Agbẹnusọ Ile, Aṣofin Wasiu Eshinlokun lo pada sọrọ itunu fun wọn, ti o si fi ye wọn pe ile igbimọ aṣofin yii naa mo ọrọ naa lara.
Lara awọn ohun ti awọn ajafẹtọ-ọmọniyan yii n beere fun ni pe ki ijọba apapọ sa gbogbo ipa wọn lati mu alaafia pada bọ sipo ni orilẹ-ede yii. Ati pe ki Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ṣeranwọ lati fi to Aarẹ Mohamadu Buhari leti naipa laasigbo orilẹ-ede yii

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button