Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Àṣofin Èkó mú ìgbèrú bá ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ka ètò ìlera pẹ̀lú àbádòfin tuntun

Lanre Lagada Abayọmi

0 294

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó gbé ìgbésẹ̀ láti mú ìgbèrú bá ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ka ètò ìlera, pẹ̀lú àbádòfin ṣíṣe àtúnṣe sí òfin kan tó níi ṣe pẹ̀lú ẹ̀ka yìí.

Abadofin naa ni wọn pe ni: “Ofin kan fun ṣiṣe Ayipada ati Atunṣe si ofin Ile-ẹkọ ajẹmoṣẹ-ọwọ imọ ilera ati awọn nnkan miiran to jẹ mọ ọ”

Abadofin oni-pele mẹrinlelaadọta (54) ti wọn pe ipade ita gbangba le lori ninu gbagede ile igbimo asofin naa ni wọn yoo fi pese alekun imọ ati idanilẹkọọ fun awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni Ipinlẹ Eko.

Igbakeji Agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Wasiu Eshinlokun-Sanni, ti o n sọju Agbẹnusọ Ile naa (Aṣofin Mudashiru Ọbasa) nibi ipade ita gbangba naa ṣalaye pataki abadofin yii, lati fi le jẹ ki iṣe ẹka ilera pojuowo, ki o si le ba ini awọn ara ilu pade. O ni:

“Laipe yii ni arun ẹbola wọ awujọ wa, ko pẹ naa ni arun COVID-19 tun wọlu, a nilo awọn akoṣmọṣẹ leka ilera wa sii. Ni igba kan ni wọn n pese awọn oṣiṣẹ eleto ilera bayii kaakiri orilẹ-ede Naijiria. O yẹ ki a pada si asiko yii. Iru abadofin yii yan-na-an-na iru ojuṣe bayii ni gbogbo ipele, ni ti igbimọ alaṣe, awọn akẹkọọ, ati awọn ti yoo fọwọ si awọn ile-ẹkọ bayii. Ti gbogbo rẹ si wa ni ibamu pẹlu liana igbalode.”

Lara awọn aṣofin ti o tun sọrọ nibi ipade apero naa ni Aṣofin Ajani Owolabi, ti o jẹ Alga Igbimọ fun ẹka eto Ekọ awọn Ile-iwe giga Ipinlẹ Eko ninu Ile Igbimọ Aṣofin naa. O ṣalaye pe abadofin yii ti faaye silẹ lati pese imọ iṣẹ lẹka ilera loriṣiriṣi, eleyii ti yoo mu imọ awọn akẹkọọ gbooro sii. O ni abadofin yii ti pese bi wọn yoo ṣe nawo lori awọn ile-ẹkọ bayii.

Ninu awọn alẹnulọrọ to sọrọ nibi ipade naa ni Arabinrin Rotimi Ayọdele, to jẹ Igbakeji Giwa Ile-ẹko ile-ẹkọ ajẹmoṣẹ-ọwọ imọ ilera ni Ipinlẹ Eko. O  gboriyin fun igbesẹ ile igbimọ aṣofin yii. O wa sọ pe o yẹ ki abadofin naa moju to owo-ajẹmọnu pataki fun awọn olukọ, itoju awọn olukọ ati ẹgbẹ ajafẹtọ awọn akẹkọọ naa.

Bakan naa ni alẹnulọrọ kan woye pe abadofin naa ko pese fun ibi ikẹkọọ itọju gbogii ninu ile-ẹkọ naa, ati pe o ye ki o le fun awọn olukọ ile-ẹkọ naa ni anfani lati maa fẹyin ti ni ẹni ọdun marun-din-laadọrin (65), ki awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ o maa fẹyin ti ni ẹni ọgọta ọdun (60).

Olori Igbimọ Aṣakoso Ile ẹkọ Fasiti Ipinlẹ Eko (LASUCOM), Ọjọgbọn Abiodun Adewuya sọ pe ki wọn mu lele ikora-ẹni-ni-janu ati ijiya fun awọn akẹkọọ sinu ojuṣe igbimọ alakoso ile-ẹkọ yii.

Ṣaaju eyi, Olori Ọmọ Ẹgbe-Oṣelu to pọ julọ ninu Ile Igbịmọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Sanai Agunbiade, ẹni ti o ṣagbeyẹwo abadofin naa labala labala sọ pe yoo le mojuto ọpọ awọn nnkan to yẹ ninu ofin ti wọn fi ṣagbekalẹ ile-ẹkọ yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button