Take a fresh look at your lifestyle.

Àgùnbánirọ̀ ṣe ayẹyẹ ọdún méjìdín-láàdọ́ta

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 255

Àwọn àgùnbánirọ̀ láti ibùdó mẹ́tàdín-lógójì jákèjádò orílẹ̀-èdè ti fakọyọ nípa ìfìfẹ́ hàn sí orílẹ̀-èdè, ní èyítí ó jẹ́ ìfilọ́lẹ̀ ètò ọ̀hún láti ọdún méjìdín-lógójì sẹ́yìn, nípa yíyan bí ológun ní ọjọ́ karún ,ọjọ́ àbámẹ́ta, osù kẹfà,ọdún 2021.Èyí jẹ́ akitiyan lórí ìdàgbàsókè àṣà láàrin àwọn ọmọ Nàìjíríà,tí ó dá lórí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni,ìṣe àìmọ̀tara-ẹni-nìkan àti mímú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè ní dan-in-dan-in.

Lakoko ti iyan bi ologun ọhun n bẹrẹ ni ibudo agunbanirọ ti ipinlẹ Nasarawa ni Keffi,oludari eto naa,Brigadier General Shuaibu Ibrahim sọ fun awọn agunbanirọ pe,agbekalẹ eto naa da lori ibaraẹni ṣepọ ati iṣọkan orile-ede.

Nigbati o nsoro siwaju, Ibrahim jẹrisi pe  Awọn agunbanirọ ṣe pataki pupọ,wọn jẹ ọmọwe ati ọdọ to da ṣaka, ti o si yẹ ki o le jupa jusẹ silẹ lati seranlọwọ lakoko pajawiri,  bii kikojuu aarun covid,idibo,ikaniyan ni orilẹ-ede ati bẹẹbẹẹ lọ.

O gba wọn nimọran lati sin orilẹ-ede baba wọn gẹgẹ bi aṣoju rere ti agunbanirọ, ki wọn si yago fun gbogbo iwa aiṣedede ti o le fi ẹmi  wọn wewu.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button