Take a fresh look at your lifestyle.

Nàí́jíríà àti Àjọ àgbáyé(UN) yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ láti pèsè ètò ààbò ní ìlà oòrùn Àríwá

Ademọla Adepọju

84

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàí́jíríà àti Àjọ àgbáyé(UN) yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ láti pèsè ètò ààbò tó péye  ní ẹkùn ìlà oòrùn Àríwá  orilẹ ede Naijiria.

Edward Kallon  to jẹ alakoso  fun ẹka to n mojuto  eto ọmọniyan ni ajọ agbaye lo sọro yii lasiko idanilẹkọọ ọlọjọ meji ti wọn se .O tẹsiwaju pe orilẹ ede Naijiria jẹ ọkan pataki  ninu orilẹ ede to wa lagbaaye ti awọn gbọdọ maa pese eto iranwọ fun, paapaa julọ. pẹlu awọn ipenija ti wọn n dojukọ lasiko yii.

Minisita   fun eto ọmọniyan, gbigbogun ti àjálù ati  idagbasoke  awujo , lorilẹ ede Naijiria, Sadiya Umar Farouq,wa dupẹ lọwọ  alakoso fun ẹka to n mojuto eto ọmọniyan  ati idagbasoke awujọ  fun ajọ agbaye , Edward Kallon fun iranlọwọ ati atilẹyin ti wọn n se fun orilẹ ede Naijiria.

O tẹsiwaju pe lati lee se aseyọri nipa  eto ọmọniyan lorilẹ ede Naijiria ifọwọsowọpọ gbọdọ wa laarin   ajo agbaye (UN) , ijọba orilẹ ede Naijiria .awọn agbofinro ati awọn ti ọrọ̀ kan.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.