Take a fresh look at your lifestyle.

Gbógun ti àwọn tó ń dá omi ètò ààbò orílẹ̀ èdè Nàíjírí̀a láàmú – Aarẹ Buhari

53

Ààrẹ   Muhammadu Buhari, ti pàsẹ fún adarí ilé-isẹ́ ọlọ́pàá tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ yàn láti rí i pé gbogbo ìwà ibi, ìjínigbé, ìpànìyàn, dídáná sun ilẹ́-isẹ́ ìjọba di àfisẹ́yìn ti eégún ń fi asọ lórílẹ̀ èdè Nàíjírí̀a .

Aarẹ pasẹ̀ yii lọjọ Ẹti lasiko to n fontẹ lu yiyan Baba gẹgẹ bi arari ile-isẹ ọlọpaa lorilẹ ede Naijria.

Minisita to n samojuto ile-isẹ ọlọpaa , Maigari Dingyadi, lo sọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin ile aarẹ sọrọ niluu Abuja , lẹyin ipade igbimọ awọn ọlọpaa, ni eyi ti aarẹ Buhari dari rẹ̀.

Ó ní: Idi pataki ti a fi ṣe ipade yii ni ki igbimọ  sọ adele adari  ile-isẹ ọlọpaa di  adari  ile-isẹ ọlọpaa nipa titẹle ilana ofin 205 . Igbimọ gbọdọ  fontẹ lu yiyan adele adari ile-isẹ ọlọpaa , ki o to lee di adari tuntun.”

O tẹsiwaju pe ipade yii tun da lori bi eto aabo se n lọ sí lorilẹ ede Naijiria ati lati wa ojutuu si awọn ipenija to wa lori eto aabo ọhun.

Adari ile-isẹ ọlọpaa  tuntun ,Usman Baba, naa tun salaye lori ipenija to wa lori eto aabo , ni paapaa julọ ni awọn ẹkún mẹfa to wa lorilẹ ede Naijiria.

O tẹsiwaju pe : “Ni  ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ajọ to n mojuto eto aabo lorilẹ ede Naijiria , ao gbiyanju gbogbo iwa aibọwọ fun ofin, iwa ibajẹ  lati ri i pe alaafia pada sipo lorilẹ ede Naijiria, ki awọn eniyan si lee fẹ̀dọ lori òróǹro

“Awon iwa ibajẹ to n sẹlẹ ni  ila oorun orilẹ ede  yii pẹlu bi wọn se n dana sun  awọn ile-isẹ ijọba , ti wọn si tun n pa awọn agbofinro , ni a o wa gbogbo rẹ̀ bolè patapata.” 

O tẹsiwaju pe awọn yoo gbe igbesẹ nipa awọn daran-daran to n wa lati ilu -okeere  si ila oorun Gusu  lati maa hu awọn iwa ibajẹ.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.