Take a fresh look at your lifestyle.

Àarẹ Buhari ń darí Ìpàdé Ìgbìmò Ọlọ́pàá

Ademọla Adepọju

97

Àarẹ Muhammadu Buhari ń ṣe ìpàdé pẹ̀lu  Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó àwọn ọlọpaa ní  ilé aarẹ ,nilu Abuja. Àwọn tí ó wá nibi ìpàdé ọhun  ni  igbákejì aarẹ, Yemi Osinbajo, alága àwọn gomina  lorilẹ ede Naijiria ,gomina ìpínlè Èkìtì, ọmowe Kayode Fayemi àti akọ̀wé Ìjọba apapọ, Boss Mustapha. Àwọn míràn tí ó wà sí ibi  ìpàdé nani adari  Oṣiṣẹ fún aarẹ Buhari, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibrahim Gambari, minisita fun ẹto ọlọpaa Alhaji Maigari Dingyadi ,minisita fun ẹto abẹle , Ra’uf Aregbesola, minisita fun ilu abuja  (FCT), Muhammed Bello àti alaga ìgbìmọ̀ eto ọlọpaa, Musiliu Smith. Adarí ilé-sé ọlọpaa lórílẹ̀ èdè Naijiria , Usman Baba tun wa ní ibi ìpàdé nàa ṣùgbọ́n ko ba wọn da si àwọn ìjíroro naa. A nírètí pé  nibi ìpàdé yii ,ni wọn yoo ti yan adari ile isẹ ọlopaa tuntun Baba lonii ,ni eyi ti aarẹ Buhari yan ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹrin (6th of April),ọdun 2021, gege bi adele fun adari ile-isẹ ọlọpaa.

 

 

Damọla Hamzat

Leave A Reply

Your email address will not be published.