Take a fresh look at your lifestyle.

A Ò LO ÀWỌN ÀGÙNBÁNIRÒ LÁTI JAGUN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÍJIRÍÀ

Ademọla Adepọju

124

Ìgbìmò to n sàkosó ètò àgùnbánirò lorílẹ èdè Nàíjiríà ti kọ etikun si àhèsọ ọ̀rọ̀ nípa ìròyìn pé àwọn àgùnbánirò le ja ogun fún orílẹ̀ èdè Nàíjiríà.

Èyí jáde nínú àtẹ̀jáde kan, tí Emeka Mgbemena fi ránsẹ́ sí àwọn akoroyin nilu Abuja.

Gégé bí ó ti sọ, adari ile-isẹ agunbanirọ, Shuaibu Ibrahim  ṣàlàyé pé pẹ̀lú ìlànà  eto ààbò orílẹ̀-èdè, àwọn àgùnbánirọ dà bí àwọn ọmọ-ogun tí ó wà ní ìpamọ́, nítorí ètò-ẹ̀kọ́, oye ati imọ ti wọn ni , le jẹ́ ko rọ̀rùn àti  lati kọ wọn bi wọn se n jagun.

Mgbemena sọ pè adari ile-isẹ agunbanirọ gba awọn agunbanirọ niyanju lati ni afojusun rere . ki wọn si ni ẹmi ifọkansin ati ibasepọ pẹlu gbogbo  ọmọ orilẹ-ede Naijiria.

O tẹsiwaju pe, adari ile-isẹ agunbanirọ, Ibrahim ko fi igba kan sọ pe wọn ti ko awọn agunbanirọ jọ lati  ja ogun.

 

Abdulrafiu kehinde

Leave A Reply

Your email address will not be published.