Take a fresh look at your lifestyle.

Bí a ṣe ń kọ́ṣẹ́, laṣe ń kọ́yára:Ìjọba àpapọ̀ yóò parí ọna márosẹ̀ Eko-Ìbàdàn lóṣù karúnun, ọdún 2022

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

189

Ìjọba àpapọ̀ pinnu láti parí ọna márosẹ̀ Lagos-Ìbàdàn ní oṣù karún ọdún 2022

Ni ọjọ iṣẹgun,ile igbimọ aṣoju ti fun awọn alagbaṣe ti o n ṣakoso iṣẹ atunla ọna marosẹ Lagos-Ibadan ni oṣu karun un,ọdun 2022,lati pari ọna mejeeji ati awọn afara.

Ile Igbimọ  aṣoju lori Iṣẹ́, ti oludari rẹ si  tun jẹ  Alaga igbimọ ọhun , Alhaji Abubakar Kabir, fun wọn  ni akoko lati pari iṣẹ ọhun, lasiko to n sabẹwo abojuto  awọn opopona to wa niluu Eko to wani Gusu orilẹ ede Naijiria , ni ọjọ iṣẹgun.

Awọn aṣofin naa bẹnu atẹ lu idaduro lori  iṣẹ naa, eyi ti o bẹrẹ ni ọdun 2013, ṣugbọn wọn ṣe ileri lati yanju awọn wahala to jẹ ki isẹ́ fa silẹ.

Awọn aṣofin naa tẹnumọ pe, awọn afara ti  o wa ni   opopona ti wọn ti kọ bẹrẹ  ni ọdun 2018 naa gbọdọ  tun  pari ni  ọdun 2022.

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.