Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ni sìgá mímu ti gbẹ̀mí wọn ní Nàíjíríà

Ademọla Adepọju

140

Mínísítà fún ètò ìlera lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà,Osagie Ehanire ti kéde  pé àwọn ènìyàn tí iye wọ́n lé ní́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ni sìgá mí́mu ti gbẹ̀mí wọn n lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà .Ó tẹ̀síwájú pé ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní máa lo àwọn àwòrán kan láti ọjọ́ kẹtàlélógún , osù kẹfà ọdún 2021 láti fi máa se ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nipa ewu tó wà níbi siga mimu.

Minisita tun tẹsiwaju pe aworan yii ni yoo dipo awọn ọrọ ti wọn maa lo , ti won maa n ka pe: “Ajọ to n mojuto eto ilera lorilẹ ede Naijria ti kede pe amusìgá máa kú ikú àìtọ́jọ́”. 

Ehanire, sọrọ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja lati síde ayẹyẹ ọjọ́ maa se mu siga ti ọdun 2021.

O tẹsiwaju pe ayẹyẹ  ọdun yii wa lasiko ti gbogbo agbaye ń dojukọ aarun COIVD-19.

“Awọn to ba n mu siga tabi awọn to ni aarun to buru , maa tete ni aarun COVID-19.”

Minisita ipinlẹ fun eto ilera, Olorunibe Mamora, wa dupẹ lọwọ  awọn  ẹgbẹ aladaani ti kii ṣe ti ijọba agbaye fún eto iranwọ lati gbogun ti siga mimú.

o ni bo tilẹ jẹ pe  ”Siga mimu ko dena ilana ofín , sugbọn o léwu  fun ilera awọn eniyan lára.”

Ajọ agbaye to n mojuto eto ilera  tun ti sọ pe o le ni miliọnu kan awọn eniyan ti siga maa n pa lagbaaye lọdọọdun.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.