Ààrẹ oriĺẹ̀ èdè Nàíjíríà, Muhammadu Buhari ti fọwọ́sí ìdásílẹ̀ ilé-ìtọ́jú àwọn àgbàlagbà.
Bakan naa, ni aarẹ Buhari tun ti yan igbimọ ẹlẹnu mejila ti yoo maa sakoso ajọ ọhun.
Eleyii wa ninu ilana ofin ti o kàńpá fun gbogbo ipinlẹ to wa lorilẹ ede Naijiria lati dá ile-itọju awọn agbalagba silẹ, ni eyi lati lee mu idagbasoke ati igbe aye idẹrun ba awọn agbalagba ti o bẹrẹ lati ọmọ ọdun aadọrin(70years).
lara awọn eniyan ti aarẹ Buhari yan naa ni : AVM. M.A. Muhammad (rtd) gẹgẹ bi alaga ajọ naa, Mansur Kuliya, asoju lati ajọ to n mojuto eto ọmọniyan, idagbasoke ati pajawiri; ọmọwe Chris Osa Isokpunwulati ajọ eto ilera; Umar Abdullahi Utono lati ajọ to n mojuto isẹ́ oju popo ati ilé gbigbie; ọmọwe John Olushola Magbadelo lati ajọ to n mojuto eto isẹ́ ati isẹ́ ọwọ́ abbl.
Aarẹ Buhari tun yan Ahmed Mustapha Habib gẹgẹ bi adari ajọ́ to n samojuto eto pajawiri (NEMA) lati rọpo AVM Muhammad (rtd).
Ọdun mẹrin pere ni awọn adari naa yoo maa lo lori ipò naa.
Leave a Reply