Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́ ti rí òkú àwọn ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́rin tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ọkọ̀ ojú omi tó dànù ní Kebbi

75

Gomina ipinlẹ Kebbi ti ní  wọ́n ti rí òkú àwọn ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́rin tó padanu ẹmi wọn ninu ọkọ̀ ojú omi tó dànù ní Kebbi.

Atiku Bagudu tun tẹsiwaju pe ijọba oun yoo seto atunse ofin ti yoo fi ilana ti awọn awakọ oju omi ati awọn èrò yoo maa tẹle lati dena pipadun ẹmi ati dukia.

Gẹgẹ  bi oluranlọwọ gomina ipinlẹ Kebbi lori  iroyin, Malam Yahaya Sarki, se sọ ni Birnin Kebbi lasiko  to n soju gomina ohun nigba ti wọn lọ ba Emir ti Yauri, ọmọwe Muhammad Zayyanu, kẹdun lori ọ̀fọ̀  to ṣẹlẹ nipa ọkọ oju ọmi to danu, ni eyi ti awọn eniyan padanu ẹ̀mí wọn ,nipa bi awakọ oju omi naa se ko ọpọ eniyan ti o ju iye awọn eniyan ti ọkọ oju omi naa lee kó lọ.

“Gomina wa ba ẹbi awọn to padanu eniyan wọn  kẹdun lori ọ̀fọ̀ naa, o wa gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn ẹbo naa nínú, o tun wa gbadura alaafia pipe fun awọn to farapa nibi isẹlẹ ọ̀hún.

“Bagudu  wa kilọ fun awọn awakọ ati èrò naa pe ki wọn maa tẹle ofin ati ilana ti wọn laa silẹ nipa iye eniyan ti wọn gbọdọ maa ko sinu ọkọ oju omi.

Zayyanu naa wa dupẹ lọwọ gomina  fun bi wọn se gbọh ìpè wọn lati tun odò baa gbẹ́ lati dena pipadu ẹmi ati dukia awọn eniyan.olouranlọwọ gomina ipinlẹ Kebbi lori isẹlẹ pajawiri,State Emergency Management Agency (SEMA), Alhaji Sani Dododo, wa kede miliọnu kan naira fun ẹbí  awọn to padanu ẹmi wọn, awọn to farapa nibi isẹlẹ ọhun, ati awọn to farajin lati yọ awọn eniyan kuro nibi isẹlẹ buruku  ọhun.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.