Take a fresh look at your lifestyle.

Boko Haram tún fara káásá lọ́wọ́ ikọ̀ ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàíjíríà

90

kò tí ì ju wákàtí mélòó kan lọ tí adarí ilé-isẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, ọ̀gágun Faruk Yahaya bẹ̀rẹ̀ isẹ́ rẹ̀ , ni ikọ̀ ọmọ ogun  Hadin Kai tó wà ní  Rann ní ìjọba ìbílẹ̀  Kala Balge ní ìpínlẹ̀  Borno dáná iyà fún ikọ̀ ọmọ ogun Boko Haram  .

Ninu atẹjade kan ti adari ẹka  ile-isẹ  to n mojuto eto  ibaraẹnisepọ, ọgagun, Mohammed Yerima gbe jade pe ” ọkẹ aimọye ,Ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ wa pẹlu ohun ija ogun , okọ̀ agbebọn lati wa si ẹnu ibode ilu naa.”

Amọsa, ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria, ti wọn ti mu  ara silẹ de wọn naa, fija pẹta lati koju ija si ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ ọhun, ti ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ naa si farapa yanna-yanna, ti wọn si tun fi ohun ija wọn silẹ, nigba ti ọwọ́ iya ba wọn.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.