Take a fresh look at your lifestyle.

Inú ààrẹ Buhari bàjẹ́ nípa àwọn tó kú sínú omi nípasẹ̀ ọkọ̀ ojú omi tó dànù

Adémọ́lá Adé́pọ̀jù

160

Ààrẹ Muhammadu Buhari  ti sapejuwe isẹlẹ to fa  iku awọn eniyan ti ọkọ oju omi wọn danu ni ijọba ibilẹ Ngaski  ni ipinlẹ Kebbi gẹgẹ bi adanu nla lorilẹ ede Naijiria.O wa ba awọn ẹbi ti ọ̀fọ̀ naa sẹlẹ si kẹdun pupọ.

Nipa iroyin ti wọn gbọ pe ọkọ oju omi naa kún àkúnfàya  ati pe ko si iroyin ti o fidii rẹ̀ mulẹ nipa iye awọn to ku sinu omi ọhun.

Bo tilẹ jẹ igbiyanju n lọ lọwọ lati yọ awọn eniyan to farapa nipa isẹlẹ ọhun,  sugbọn aarẹ tun wa gbosuba fun awọn to n kopa lati yọ awọn to farapa ọhun , aarẹ si tun wa ki awọn ti won farapa pe Ọlọ́run yóò fún wọn ni àlàáfíà.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.