Take a fresh look at your lifestyle.

Children’s Day:Abẹnuga ilé ìgbìmọ̀ asòfin bá àwọn ọmọdé yọ̀

Ademọla Adepọju

136

Àbẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asòfin orílẹ̀ èdè Nàíjíríà,  Ahmad Lawan, ti kí gbogbo àwọn ọmọdé orílẹ̀ èdè Nàíjíríà àti àwọn tó wà lẹ́yìn odi kú orí-ire fún àyájọ́ ọdún àwọn ọmọde ..

Abẹnugan ile igbimọ asofin tun wa rọ gogbo awọn alasẹ́ ni gbogbo ẹka to wa lorilẹ ede Naijria lati maa se ohun ti yoo tubọ mu eto idagbasoke bá awọn ọmọde lorilẹ ede yii..

“Ni asiko ayẹyẹ yii, mo fi n da gbogbo ọmọde orilẹ ede yii lójú pé , ilé igbimọ asofin yoo tubọ maa seto ofin ti yoo maa daabo bo ẹ̀tọ́ awọn ọmọde orilẹ ede yii .

Lawal tun sọ pe “Mo tun fẹ lo asiko yii lati rọ gbogbo awọn ipinlẹ to wa lorilẹ ede Naijiria lati maa lo ofin ọdun 2003 ti o fi ẹ̀tọ́ awọn ọmọde  silẹ  ni awọn ipinlẹ wọn.

“Ẹ jẹ ki a kọ́ awọn ọmọ wa lọna ati maa lọwọ ninu  eto idagbasoke ati  alaafia orilẹ ede Naijiria” .

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, osu karun un, ni ayẹyẹ ayajo awọn ọmọde maa n waye , ni eyi ti gbogbo awọn ọmọde yala ni ile iwe alakọọbẹrẹ tabi girama maa n wa ninu isinmi.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.