Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n ṣe ìsìn ayẹyẹ ìkẹyìn fún adarí ilé-isẹ́ ológun Attahiru àti àwọn ikọ̀ ọmọ ogun rẹ̀

Ademọla Adepọju

79

Ààrẹ Mohammadu Buhari ti ní ikú adarí ilé-isẹ́ ológun , ọ̀gágun  Ibrahim Attahiru  kò ní já sí asán.

Aarẹ Mohammadu Buhari sọrọ lasiko ti wọn n se isin ayẹyẹ ikẹyin fun adari ile-isẹ ologun ati ikọ ọmọ ogun rẹ ti wọn ku ninu ijamba ọkọ baalu. niluu Kaduna, lọjọ kọkanlelogun, osu karunun ọdun, 2021.

Minisita fun eto aabo lorilẹ ede Naijiria,ajagunfeyinti, Bashi Magashi lo soju aarẹ Muhammadu Buhari., o sapejuwe oloogbe Attahiru gẹgẹ bi olufọkasin ati ẹni ti o ni ifẹ orilẹ ede Naijiria lọkan.

Bakan naa, adari ile-isẹ ologun to n mojuto eto aabo lorilẹ ede Naijiria,  ọgagun Lucky Irabor  naa tun sọ pe ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria ko ni kaarẹ  ninu ojuse rẹ lati tubo maa daabo bo orilẹ ede Naijiria .O tẹsiwaju pe iku akẹgbẹ rẹ  ko ni ja si asán ati pe awọn ipenija ti orilẹ ede Naijiria n dojukọ yii wa fun ìgbà diẹ ni.

Lara awọn to wa sibi isin ayẹyẹ ikẹyin ọhun naa ni  alaga ile igbimọ asoju fun ile-isẹ ologun,abẹnugan ile igbimọ asoju, gomina ipinlẹ Kaduna, El-Rufai ati awọn adari ile-isẹ ologun ati agbofinro lorilẹ ede Naijiria.

Leave A Reply

Your email address will not be published.