Take a fresh look at your lifestyle.

ikú dóró ! ,adarí ilé-isẹ́ ológun ,Ibrahim Attahiru pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ bàálù

Ademọla Adepọju

131

Aarẹ orilẹ ede Naijiria, Muhammadu Buhari  ti ni ọkan oun bajẹ lati gbọ iroyin iku adari ile-isẹ ologun lorilẹ ede Naijiria ,ọgagun Ibrahim Attahiru ati awọn ikọ ọmọ ogun rẹ , ninu ijamba ọkọ baalu.

Ninu atẹjade kan lati ile isẹ aarẹ to  waye lasalẹ ọjọ Ẹti , lati  ba awon ẹbi awọn oloogbe ikọ ọmọ ogun ati orilẹ ede Naijiria lapapọ  kẹdun pupọ lori isẹlẹ ọhun.

Aarẹ wa gbadura pe  ki Ọlọrun tẹ awọn oloogbe naa si afẹfẹ ire.Aarẹ tun wa seleri pe iku awọn to padanu emi wọn ninu ijamba ọkọ baalu ọhun, ko ni ja si asán.

Isẹlẹ ijamba ọkọ baalu naa waye nibi ti ko jinna si papa ọkọ ofurufu to wa ni ipinlẹ Kaduna.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.