Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Cross River ,Ben Ayade,dágbere fún PDP pé ó dìgbóse ,darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú APC

Ademọla Adepọju

139

Gómìnà ìpínlẹ̀, Cross River , ọjọgbọn Ben Ayade, ti dágbere fún ẹgbẹ́ oselu  PDP, (Peoples Democratic Party ,PDP) pé ó dìgbóse , nígbà tí o darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú  tó ń se ìjọba lọ́wọ́ APC, All Progressives Congress (APC).

Gẹgẹ bi atẹjade  kan  pe , gomina  Ayade kede ipinnu rẹ lọjọBọ  nibi ipade ti o ṣe pẹlu awọn gomina  mẹfa to jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu APC nile gomina to wa ni ipinlẹ, Calabar.

lara awọn gomina ti o wa nibi ipade ọhun ni gomina ipinlẹ  Kebbi, Imo, Yobe, Plateau, Jigawa, ati Ekiti .

Gomina Ayade ni oun darapọ mọ ẹgbe oselu APC latari aseyọri ti ẹgbẹ naa n se ati iwa adari rere ti ijọba Muhammadu Buhari n hu lorilẹ ede Naijiria.

Nigba ti gomian ipinlẹ  Yobe , Mai Bala-Buni, ti o jẹ adele alaga fun ẹgbẹ oselu APC  n ki gomina Ayade kaabọ sinu ẹgbẹ oselu APC  o ni ., “Lati oni lọ , Ayade iti adari ẹgbẹ oselu  APC ni ipinlẹ Cross River.’

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.