Take a fresh look at your lifestyle.

Digbí lawà lẹ́yìn àwọn osisẹ ipinlẹ Kaduna- Comrade Bayo Titilola Sodo

Ademọla Adepọju

184

Olùdámọ̀ràn fún gomina ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórí ọ̀rọ òsìsẹ́, Comrade Bayo Titilola Sodo, ti sọ pé, digbí ni ẹgbẹ́ òsìsẹ́ wà lẹ́yìn àwọn òsìsẹ́ ìpínlẹ̀ Kaduna ní irú àsìkò bí èyí.

Comrade Titilola Sodo lo sọrọ yii lasiko ifọrọwerọ pẹlu  asoju ẹgbẹ awọn  akọroyin, eka ti Ipinle Ọyọ (Correspondents’ chapel of Oyo NUJ).  ni eyi to waye ni Ile ẹgbe ọhun to kalẹ si agbegbe Ago Tapa, Mokola niluu Ibadan ti i  se olu ilu  Ipinle Ọyọ, ni ẹkun Gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria.

Nigba ti, o koro oju si igbese gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El Rufai lori awon osisẹ  to da duro, Oludamọran fun gomina ipinle Ọyọ lori ọrọ osise, Bayo Titilola Sodo wa bu ẹnu atẹ lu   igbesẹ ti  gomina El-Rufai gbe nipa wahala to wa laarin  ohun ati awọn osisẹ rẹ̀, Bayo Titilola Sodo wa gba gomina El-Rufai ni imọran lati pada si iduna-dura pẹlu awon osisẹ ipinle naa.

Siwaju si ninu ọrọ rẹ, Titilola Sodo jẹ ki o di mimọ pe, isejọba Seyi Makinde ti se aseyọri nipa sisan owo ajẹmonu awọn osisẹ fẹyinti lasiko.

Bakan naa, lo tun fi kun ọrọ rẹ pe, ipinlẹ Ọyọ jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ to n san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bi i owo osu osisẹ to kere ju, nigbati owo to n rẹgun sinu asuwọn ijoba si le ni Bilioni Meji naira losoosu, eleyi to mu ko rorun fun ijọba lati maa se deede ninu owo osu sisan

Saaju ninu ọro ikinni kaabọ rẹ, ẹni ti se alaga ẹgbẹ asoju akọroyin ni ipinlẹ Ọyọ, Comrade Ola Ajayi fi asiko naa lu gomina Seyi Makinde lọgọ ẹnu fun awọn akanse isẹ́ to n se ati bi o se n san owo osisẹ ijọba lasiko, nigbati o rọ oludamọran gomina lori ọrọ osisẹ lati tẹsiwaju ninu igbesẹ akin to n gbe lati ri daju pe gomina ko fi ọ̀rọ̀ osisẹ sere ni ipinlẹ Ọ̀yọ́.

 

 

 

 

 

 

Abiọla Ọlọwẹ

Leave A Reply

Your email address will not be published.