Take a fresh look at your lifestyle.

International Museum Day 2021:Germany yóò dá àwọn isẹ́ ọnà ti wọ́n jí kó padà sí orílẹ̀ èdè Nàíjíríà

Ademọla Adepọju

98

Ijọba orilẹ ede Germany ti bẹrẹ igbesẹ lati maa da awọn isẹ ọna ti wọn ji ko  lati Benin,  lọ  si orilẹ ede wọn pada si orilẹ ede Naijiria.

Minisita fun iroyin ati asa lorilẹ ede Naijiria, Alhaji Lai Mohammed lo sọrọ yii niluu Abuja lọjọ  Isẹgun lati tubọ ro gbogbo awọn orilẹ ede ti awọn ohun alumọọni ati isẹ ọna orilẹ ede Naijiria wa ni ikawọ wọn lati daa pada.

Bakan naa, , o tun wa rọ gbogbo awọn orilẹ ede ti ọrò , isẹ́ ọnà ati awọn ohun alumọọni Naijiria wa nikawọ wọn lati daa pada si orilẹ ede Naijiria.O tun wa rọ awọn onimọ ọmọ orilẹ ede Naijiria lati darapọ mọ ijọba ninu igbiyanju rẹ lati ri i pe wọn da awọn ohun alumọọni orilẹ ede yii pada.

Minisita tun wa dupẹ lọwọ awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria kan ti wọn ti da ile ti wọn yoo maa ko awọn ohun isura , isẹ ọna ati awọn ohun alumọọni orilẹ ede yii pamọ sí, pẹlu owó wọn silẹ.

Mohammed tun tẹsiwaju pe awọn ko ni kaarẹ ninu iyanju wọn lati ri i pe gbogbo awọn isẹ́  ọnà ati awọn ohun alumọọni ti awọn orilẹ ede kan ji ko lati orilẹ ede Naijiria  lọ si orilẹ ede wọn  pada.

orí ère  idẹ ti ìlú Ifẹ̀
Orí ère  idẹ ti ìlú Ifẹ̀ ti wọn ji gbe ni yaya ì-kó-ẹ̀sọ́- sí,(National Museum) to wa ni ilu Jos lọdun  1987, ni eyi to wa ni Belgium, ni wọn n beere owo lati ọwọ́ orilẹ ede Naijiria, ki wọn to lee daa pada  bayii.

Minisita tun tẹsiwaju pe, , ni osu kinni ọdun  2020,ni o ba akọwe agba ipinlẹ   fun asa  ni  orilẹ ede  United Kingdom  sọrọ nipa  bi wọn yoo se da Orí ère  idẹ ti ìlú Ifẹ̀ pada si orilẹ ede Naijiria , ni eyi ti o wa ni yara  ì-kó-ẹ̀sọ́- sí ni Britain( British Museum), Minista ni o da oun loju pe , orilẹ ede Naijiria ko ni pẹ gba ori ere idẹ naa pada si orilẹ ede Naijiria.

Gomina ipinlẹ  Edo , ni ẹkun Gusu orilẹ ede Naijiria, Godwin Obaseki wa gbosuba fun akitiyan ijọba orilẹ ede Germany  fun igbesẹ rẹ lati da gbogbo awọn isẹ ọna ati ohun alumọọni ti wọn ji gbe lọ si orile ede wọn pada, pe iru igbesẹ ọhun yoo tun jẹ ki ibasepọ to wa laarin orilẹ ede mejeeji naa tubọ fẹsẹ̀ mulẹ sii , paapaa julọ nipa asa.

Adari ikọ orilẹ ede Germany, ọmọwe  Andreas Gorgen lati ọfiisi  asoju orilẹ ede  Germany naa tun sọ pe ijọba orilẹ ede Germany nigbagbọ pe iru awọn ohun to niye lori bawọnyi , yẹ ki o pada si ibi ti o ti wá.

Ayẹyẹ ọjọ́ yara ì-kó-ẹ̀sọ́-sí ni agbaye (The International Museum Day) maa n waye ni ọjọ kejidinlogun osu karun un ni ọdọọdun .

Leave A Reply

Your email address will not be published.