Take a fresh look at your lifestyle.

Àgbò tó fẹ̀yìn rìn, agbára ló lọ mú wá,Chelsea gbẹ̀san ìyà F.A CUP padà lára Leicester

Ademọla Adepọju

257

Ṣe àgbò to fẹyin ni , agbara ló lọ mú wá, eyi lo difa fun ikọ agbabọọlu Chelsea ti wọn padanu ife ẹyẹ F.A , nigba ti ikọ agbabọọlu Leicester City fẹyin wọn janlẹ. Amọsa, ikọ agbabọọlu  Chelsea naa pada lọ tun ara mu ,ti wọn si  fi ẹ̀san ìyà  ife ẹyẹ F.A ti Leicester City gba lọwọ wọn jẹ wọn.

Ami ayo meji ni  ikọ agbabọọlu Chelsea  fi lu ikọ agbabọọlu Leicester City  ti wọn ṣi tiraka lati da ọkan pada sawọn ikọ agbabọọlu Chelsea .(2-1)Papa isere Stamford Bridge ere ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye.

Jamie Vardy , ni o kọkọ bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa, ni ọwọ iwaju nigba ti  Kelechi Iheanacho to jẹ ọmọ orilẹ ede Naijiria, si wa lori aga ijokoo.Se inu didun lo maa n  mu moriya wa, nigba ti awọn ọmọ  lẹyin ikọ agbabọọlu Chelsea ti wọn le ni ẹgbẹrun mẹjọ  bẹrẹ si ni maa kọrin , ti wọn si n mu inu wọn dun, lori ikọ agbabọọlu Chelsea ba  wu soke, bi alájọ Sómólú, ni wọn wa bẹrẹ si n ju awọn èèmọ̀ bọọlu tó le si ojúlé ikọ agbabọọlu Leicester City .

Ninu abala kinni ere ifẹsẹwọnsẹ ọhun, ko si ikọ agbabọọlu meji naa to ta pútú, bo tilẹ jẹ pe  Christian Pulisic  to jẹ ọkan lara ikọ agbabọọlu Chelsea, fẹ si àwọ̀n goolu naa sugbọn ti golí ,Kasper Schmeichel ti ikọ agbabọọlu  Chelsea si mu bọọlu ọhun, eleyii lo jẹ igba kọkanla ti ikọ agbabọọlu Chelsea fẹ gba bọọlu si oju òpó ikọ agbabọọlu Leicester City.

Ni kete ti wọn bẹrẹ  abala ikeji eré ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni Antonio Rudiger to jẹ  ikọ agbabọọlu chelsea gba  ami ẹyọ kan wọle si àwọ̀n ikọ agbabọọlu Leicester City .

Agbabọọlu Leicester  to n di ipo ẹyin mu , Wesley Fofana ni ọwọ́ rẹ kan bọọlu , boya o ro pe bọọlu a-fọwọ-gba ni , amọsa, kọ́rọ̀ to do wo-mi-ki-n wo -ọ, pẹnariti lo gbẹyin rẹ, ti Jorginho ti ikọ agbabọọlu  Chelsea gba bọọlu sinu àwọ̀n  ikọ agbabọọlu Leicester City .

Edouard Mendy  to jẹ ikọ  agbabọọlu Leicester City naa tun da goolu kan ti  ikọ agbabọọlu Chelsea gba sinu awọn  wọn pada.lo ba di 1-1.

LONDON, ENGLAND – MAY 18: Kelechi Iheanacho of Leicester City celebrates after scoring to make it 2-1 during the Premier League match between Chelsea and Leicester City at Stamford Bridge on May 18, 2021 in London, United Kingdom. (Photo by Plumb Images/Leicester City FC via Getty Images)

O ku isẹju kan ti ere ifẹsẹwọnṣe naa yoo pari ni , ikọ agbabọọlu Leicester City ba tun sàgbákò  penariti kan  ti ikọ agbabọbọlu Chelsea si fi ami ẹyọ kan somi ara.

Eré bọọlu ifẹsẹwọnṣẹ naa pari  pẹlu  àmì ayò  meji si ọkan (2-1 ).

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.